Seneto Adeola dupe lowo awon oludibo, o seleri eto ijoba to deledoko, o wa ro won ki won jade lati dibo Aare lojo Abameta

Seneto Solomon Olamilekan pelu Iyawo re ati oludije sipo Gomina labe Asia ẹgbẹ Oselu ADC ninu eto idibo odun 2023 Amofin Biyi Ọtẹgbẹyẹ ni won jo de sibi eto idibo abele naa nilu ilaro.
Adeola, ẹni tó ń ṣojú fún Iwo -Oorun ipinle Ogun lọ́wọ́lọ́wọ́ ní Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àpapọ̀, sọ èyí di mímọ̀ ní ọjọ́rú, ojo kokonoelogun osu karun odun egbaa odun o-le merindinlogbon yi , lẹ́yìn tí ó kópa nínú ìdìbò abele sipo gómìnà ní Pahayi, ni woodu kini nilu ilaro .
Nígbà tí ó ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀, Sẹ́nétọ̀ Adeola Yayi fi dá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú lójú pé òun kò ní já wọn kulẹ̀ tí oun bá di gómìnà, Tori oun ma rii or eto ijoba oun deledoko kaakiri ipinle Ogun, be lo ro awon to si n binu ninu ẹgbẹ Oselu pe ki won ma binu mo ki won je kawon Jo sise naa ki ilosiwaju le ma ba ẹgbẹ Oselu APC.
Adeola wa Fi da awon eeyan loju pe oun ma je ki ijoba oun mu nnkan derun fawon eeyan nipinle Ogun, Tori oun ma gunle ise rere ti Gomina Dapo Abiodun ti oun Fe gbase lowo re n se lo lowo.
Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, “Mo fẹ́ fi dá àwọn èeyàn lójú pé maa ṣe ìjọba tó ma mu nnkan derun fawon olugbe ipinle ogun.
Sẹ́nẹ́tọ̀ náà gbóríyìn fún ẹgbẹ́ òṣèlú fún bí wọ́n ṣe ń ṣe ìdìbò gómìnà ní àlàáfíà àti ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ, ó sì sọ pé ìṣètò náà fi ìṣọ̀kan àti ifowosowopo tó wà láàárín ẹgbẹ́ òṣèlú náà hàn.
Sẹ́nétọ̀ Adeola Yayi tún fi ayọ̀ hàn pé wọ́n ṣe ìdìbò àkọ́kọ́ ní àlàáfíà jákèjádò ìpínlẹ̀ náà, ó sì ṣàlàyé bí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú ṣe jáde nígbà ìdíje àkọ́kọ́ gẹ́gẹ́ bí àmì tó lágbára pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC ṣì lágbára àti pé wọ́n ní ipò tó dára láti gba ìṣẹ́gun tó lágbára nínú ìdìbò gbogbogbòò ọdún 2027.
O wa ro awon eeyan pe ki won jade ni ojo abameta lati wa dibo abele fun ti Aare Bola Ahmed Tinubu.
Ó tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu àti Gómìnà Dapo Abiodun fún gbígbé ìjọba tiwantiwa lárugẹ ró, ó sì tún sọ pé òun ti múra tán láti ṣe ìṣàkóso tí ó ma Faye gbà gbogbo eeyan lati se bo se Wu won .
Eyi ni bi ibo ti won di se lo si nilu ilaro.Woodu akoko nilu ilaro ni won ti ka ibo 3,023 ,woodu keji to wa ni ikoja Banki ni won ti ri ibo 2,601 be ni won ri ibo 2,419 ní woodu keta to wa ni sabo ni ilu ilaro.
Leyin ti won setan ni woodu akoko ni Seneto Solomon Olamilekan ati Biyi Ọtẹgbẹyẹ pelu awon eeyan to ku lo sawon woodu to ku



