O damiloju pe egbe Oselu APC lawon olugbe Ipinle Ogun maa dibo fun, Tori gbogbo ileri taase lasiko Ipolongo Ibo lati muse-Gomina Dapo Abiodun

Gomina Dapo Abiodun ti Fi idaniloju re han pe egbe oselu APC lawon Olugbe Ipinle Ogun maa dibo fun ninu Eto idibo ijoba Ibile to fe waye lojo kerindinlogun osu kokonla odun 2024.
Dapo Abiodun soro naa nibi Ipade kan to waye lojo eti nilu Abeokuta pelu awon adije to n dije sipo alaga ati kanselo ninu egbe oselu APC jakejado Ipinle Ogun.
Gomina Dapo Abiodun ni, “mo ni idaniloju pe egbe oselu APC lawon Olugbe Ipinle Ogun ma dibo fun Tori gbogbo ileri ti a se lasiko ipolongo lbo pata la ti muse .
Gomina ni Oun ti pari titi to le ni eedegberin 700 be ni Oun ti pari Ile Alaboode to le ni gberunmerin 4000.
Bakan naa ni Gomina ni Oun ti si Ile iwosan to je ogofa 120 ati Ile Eko egberunkan 1000 .
Gomina je ko da awon Olugbe Ipinle Ogun loju pe awon igbese ti Aare Tinubu n gbe bayi si ma so eso rere.
Die lara awon nnkan to Fi han pe awon eeyan ma gbadun Aare Tinubu ni bi are se pase pe ki won ma ta iresi fawon araalu ni ogoji egberun#40,000.
Alaga egbe oselu APC,Oloye Yemisi Sanusi ro awon eeyan lati jade ki won se lpolongo lbo pelu awon oludije ko le rorun fun won lati jawe olubori.




