Ko si nnkan to n je PDP mo ni Guusu Yewa- Alaaji Kayode Sunmola Adewale

Olóye Kayode Sunmola Adewale to ti figba kan je Alaga ibile Guusu Yewa to si je okon gboogi ninu ẹgbẹ Oselu PDP ni Guusu Yewa lo soro naa pe ko si ẹgbẹ Oselu PDP ni Guusu Yewa mo.
Sunmola soro yi nigba to n darapo mo ẹgbẹ Oselu APC ni Guusu Yewa lojo kejidinlogun osu keje odun egbaa odun o-le merindinlogbon.” Ni bayi ti mo ti darapo mo ẹgbẹ Oselu APC ni Guusu Yewa mo n Fi dayin loju pe gbogbo ojulowo ẹgbẹ Oselu PDP Pata ni mo ti ko wa sibi loni”.” Mo dupe lowo Ọlọrun fun oore ofe to fun mi lati darapo mo ẹgbẹ Oselu APC loni,
“Emi ati Abileko Iyabo Apanpa jo wa ni PDP tele ni won mo ipa ti mo ma n ko lori oro oselu, nibayi ti a si ti jo wa ninu ẹgbẹ Oselu APC mo n fi dawon loju pe ma sise gan an ti inu won ma dun bi a o se baje lowo Ara wa tele naa lao ni baje lowo Ara wa bayi”.
Looto YaYi o si nibi loni amo mo ti di Omo ẹgbẹ Oselu APC.
Leekan si “Mo Fi gbogbo enu so pe ko si nnkan to n je PDP ni Guusu Yewa lati oni lo”.emi Kayode Sunmola lo so be .gege bo se so.
Be ni Onorebu Latifat Ajayi naa dupe lowo Alaaji Sunmola Adewale fun bi won se wa darapo mo ẹgbẹ Oselu APC.
” Kiise Owo lo je ki won wa darapo mo ẹgbẹ Oselu APC ife ti won ni pe ki Omo Yewa di Gomina lo je ki won wa darapo”.
Igba to si to ni won wa yi, o damiloju pe awon gan ma gbadun tori Ile ni won wa,
Ko daa keeyan ma se oselu ko ma fori pamo bi won se gbe oselu won jade yi lo da.
“Kiise Tori Owo ni Sunmola se wa nnkan to je ki won wa nipe ati ri ojulowo Omo Yewa bayi asiko to si ye won ni won wa yi”.
Looto oselu ma n je ka yato sira amo Alaaji kii dale rara ibi ti won ba n lo won ma so o ni won o ni Fi dudu pe funfun. “Nigba ti mo wa ni kansu Alaaji ni mo ba sise mo si jere bo gbogbo eyin te wa leyin won le ma jere” .
“Gbogbo awa taa sise labe Alaaji lasiko ti won se Alaga la gbe nnkan rere se kódà Opo ninu wa lakole”.
Bi awa se se oriire ni awon iyawo won naa se oriire.
Won le bu yin ni sesede e ma dawon loun eyin ni ke duro giri.
Mo Fe ke mo pe asiko tiwa la wa yi gbogbo wa la ma ri tiwa se.
Be ni Alaga ẹgbẹ APC bayi ati ti tele iyen otunba Tunji Idowu ti Opo eeyan mo si Akara naa dupe lowo Iyabo Apanpa ati gbogbo awon ti won wa sibi ayeye naa ku idide.
Won ni ” A ti n fojusona fun ojo ti Alaaji Sunmola ma darapo mo wa ninu ẹgbẹ Oselu APC tipetipe , a si n ki yin kaabo”.
Bi won se so odawaloju pe ko si ẹgbẹ PDP mo ni Guusu Yewa, “mi o Fe gbo pe ẹgbẹ PDP kankan ni ida meji ninu eto idibo to n bo yi”.
Be lo ro awon Omo ẹgbẹ Oselu PDP to won sese darapo naa ki won bere si ni maa lo si awon ipade ẹgbẹ Oselu APC, bere lati ipade woodu . Ti enikan ba si bi yin ni nnkan kan e jowo epe Alaaji Sunmola to je Adari yin a le tete yanju awon oro to ba sele.
Abileko Apanpa Fi da awon eeyan loju pe eeyan daadaa ni Sunmola kódà nigba ti awon o Jo si ninu ẹgbẹ kan naa o ma n toju awon.
Idi niyen ti mo se n ro gbogbo wa boya Iwo ati eeyan jo wa ninu ẹgbẹ tabi beeko e ma soore fun gbogbo eeyan .
“To ba wa lodo eeyan ti ko ba se fun e kuro lodo e”.
” Awako mi ni moto ,mo si kole fun Tori to ba da fun e ogbodo da fun awon to wa leyin yi.”
” Gbogbo eyin te wa pelu Sunmola e mo pe e ni mama ni waju , mo wa pelu yin.”.
“Bi Sunmola se de yi okon mi ti bale pe awon woodu to ku ko le bori wa awa la ma bori won “.
Leyin ti Alaga ẹgbẹ Oselu APC fi awon ti won je Alaga ni gbogbo kookan to wa ni Guusu Yewa han awon ti won sese wole naa.
Be ni akowe egbe Oselu APC ni ijoba ibile Guusu Yewa Raheem Balogun ati awon mii naa fi idunnu won han won si ki won kaabo sinu ẹgbẹ
Leyin iyen ni awon onibolojo,Igunnuko wa fijo ki Alaaji Sunmola Adewale kaabo sinu ẹgbẹ Oselu APC.

Awon ti won tun wa nibe ni
Moruf Adeola
Onorebu Wasiu Olakuleyin,
Taiwo Jimoh AKA Sinkafe,
Onorebu.Kabru ati
Onorebu Abimbola Adebusoye
Akowe egbe Apc Raheem Balogun
Onorebu Kayode Salako JP



