
Seneto Olamilekan Adéola Yayi ti je ko da awon eeyan loju pe ko sija laarin Oun ati Gomina lpinle Ogun, omooba Dapo Abiodun.
Sen.Adeola soro yi nigba to n ba awon lobaloba ni Ile Awori soro loni ogbon ojo osu kewa odun 2024.
Nibi Ipade ti seneto se pelu awon lobaloba ni aafin Oba lanlege to je Olori awon oba Ile Awori lo ti so Oro naa, o ni” ko si Ija laarin emi ati Gomina, Omo Ile kan naa ni wa ,Omo Asiwaju ni wa. Awon ti nnkan ti o n Wu MI n Wu ni won n gbe aheso kiri pe Ija wa laarin wa”.
” Asiwaju ni Gomina je fun mi, nnkan ti won ba ni ki n se ni Mo ma n se.Mo ti Fi atejise ranse si won pe Mo n bo wa sibi ayeye Oja ni ilu OTA laaro yi ki n to ma a bo”.
“Nnkan to n je mi logun ni bi afojusun wa ni Iwo-Olorun lpinle Ogun se ma te wa lowo, mo si nigbagbo pe o ma seese”.

Be ni awon Oba Prof Abdulabir Obalanlege ati gbogbo awon lobaloba nile Awori se adura fun Seneto Olamilekan Adéola Yayi won si je ko da Seneto Solomon Adéola Olamilekan Yayi loju pe awon wa leyin re.




