ÌṢÒWÒ

Eso asobode ipinle ogun pa #275,835,406 wole sapo ijoba apapo lodun 2024 ….. won gba Igbo,Iresi,Ada ati eru fayawo mii losu kini odun 2025.

Oga agba eso asobode nipinle Ogun, Kontirola Shuaibu Muhammed ti je ko di mimo pe milionu lona igba ole ni ajo naa to wa ni eka akoko nipinle Ogun pa wole si apo ijoba apapo lodun egbaa odun o-le merinlelogun to koja.

Shuaibu soro yi loni ojo kejidinlogbon osu kini odun egbaa odun o-le marunlelogun yi nigba to n ba awon oniroyin soro ninu ofisi re to wa ni Idiroko ni ipinle Ogun.

Kontirola ni aropo awon iresi ti ajo naa gba lodun 2024 je;  Baagi iresi egberun merindinlogun o le 16,712kg

Lita epo Bentiro 139,881

Ota Ibon 940

saaki igbo 71

Aso Aloku Beeli 587

Moto ti won fi n ko eru fayawo 86

Moto Tokunbo mejidinlogun 18

Taya aloku igba ole 2,150

Awon Donkey 760

Oku adiye egberunmeta o le 3,766 ati apo filawa ile okeere  marunle logorin 85.

Gbogbo aropo owo ori awon eru yi je #1,267,504,035.

kontirola Shuaibu  tun je ko di mimo pe ajo naa ti tun gba;  lgbo Iresi, Ada ati awon nnkan mii lowo awon onifayawo laarin osu kini odun 2025.

Awon nnkan ti won gba lowo awon onifayawo naa ni;
Apo lresi egberun meji ati eyo meji 2 002.
Ada egberunmefa ole 6,180
Epo Bentiro 6375 litasi
Aropo iye owo awon eru ti ajo eso asobode gba lowo awon onifayawo laarin ojo kini osu kini odun egbaa odun o-le marunlelogun si ojo ketadinlogbon osu ki ni je #77,476,185.

Be ni adari awon eso asobode ni idiroko, Kontirola Shuaibu Muhammed ti fa igbo to wa ninu eru fayawo naa le ajo Naco lowo.

O dupe lowo oga agba ajo eso asobode lorile ede Naijiria, Kontirola Bashir Adewale Adeniyi fun atileyin re ati awon alakale to n gbekale fun ajo eso asobode lati ma fi pawo wole sapo ijoba apapo pelu awon  iriri to n lo lati fi ma dari iko asobode lorile ede Naijiria.
Shuaibu tun wa dupe lowo awon adari ilu ati awon eso alaabo to ku fun Ifowosowopo won lori awon ise ti awon ti se.

O ro awon araalu lati ma ba lo nipa fifi awon nnkan to ba n sele lagbegbe kaluku nipa oro fayawo to ajo eso asobode leti.

N8gba ti ogbeni Olusegun Adeyeye to je Komanda awon Nako ni agbegbe ldiroko n  tewogba idipo igbo ti iye re je egberunkan ole naa 1165 . O seleri pe oun naa ma fa le ajo NDLEA to n gbogun ti oogun oloro lowo ki won le lo se ayewo to ye lori re, ki won si baaje.
Adeyeye wa ro gbogbo awon omo Naijiria lati fowosowopo pelu awon eso alaabo to n gbokun ti oogun oloro ko le rorun lati fo ayika mo ko ma si enikeni to n mu oogun oloro laarin awon eeyan.

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button