Maa ko Ile ijosin musulumi mii to ni Iwe ase ijoba sinu ogba Ile Eko awa asobode to wa ni idiroko-kontirola James Ojo

Kontirola James Ojo ti Fi da awon eeyan loju pe Oun Maa ko Ile ijosin awon musulumi mii to ni Iwe ase ijoba pada sinu ogba Ile Eko awon asobode to wa ni idiroko .
Ninu atejade kan ti Ogbeni Bukoye OLOYEDE to je Alukoro Ajo eso asobode Fi ranse si Iroyin Yewa lojo keta osu kokonla odun 2024 yi lo ti so Oro nipa fidio kan to wa lori ayelujara nibi ti won ti fesun kan Eni to wa leka Ile Kiko ninu ogba Ile Eko naa pe o Fe wo Ile ijosin ti won n ko lo naa danu lainidi.
Oloyede je ko di mimo pe iwadi ti awon se Fi han pe eni to wa leka Ile Kiko naa ko pase pe ki won wo Ile naa danu lainidi amo o pase pe ki won wo Ile ijosin ti won n ko lo naa pale tori ko ni Iwe ase lati Odo ijoba ati pe bi won se n ko Ile naa ko ba alakale Ile Kiko to wa fun ogba Ile Eko giga naa mu .
Te o ba gba gbe Ninu fidio naa ni won ti Fi esun kan Ajo naa pe won kan tie Fe wo Ile ijosin ti won n ko lo naa danu lainidi ni.
Sugbon alaye ti Bukoye OLOYEDE to je Alukoro Ajo naa se ninu atejade to Fi ranse si Iroyin Yewa lo je ko di mimo pe “Ile ijosin ti won n ko lo naa ko tii gba awon Iwe ase to ye ki won gba lodo ijoba ni eni to wa leka Ile Kiko se pase pe ki won wo Ile naa ki won si lo seto bi won se Fe bere si ko Ile ijosin mii si ibi ti ijoba fowosi”.
Be ni Oga agba to n dari awon eso asobode ni eka akoko ni ipinle Ogun ,James Ojo ti Fi da awon oluko ati awon ti Oro kan naa loju pe Oun ma ko Ile ijosin mii to ni Iwe ase ijoba fun won nibi ti ijoba Fowosi.
O wa ro gbogbo awon ti won je Adari Ile Eko naa ati awon ti Oro naa kan pe ki won se suru lori Oro naa.


