Ẹso alaabo So-Safe Corps, ti mú àwọn afurasi mẹ́ta tí wọ́n maa n ra epo Disu lowo osie Ile ise to n se ojú ọ̀nà Sokoto lagbegbe Ilaro.

Owo eso alaabo so-safe to wa ni Guusu Yewa ipinle ogun to ba awon afurasi ti won ma n lo ra awon disu lowo awon osise ti won n se opopona marose Sokoto Badagiri ni ilu ilaro.
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ti sọ, ẹso alaabo So-safe gba ìròyìn pe awon kan ninu awon osise Ile ise to n se titi marose Sokoto si Badagiri lagbegbe idogo ni ilaro ma n ta ninu awon epo Disu ti won ma n lo fawon kan lagbegbe naa.
Iroyin Fi to wa leti pe lesekese ti Ogbeni ACC Moruf Adaranijo, to je Adari eka naa lagbegbe Ilaro gbo oro naa lo to fi to apase eso alaabo naa Soji Gansalo leti to si fun un lase lati lo se iwadi siwaju sii lori isele naa.
Nigba to fi ma di ojo kejìlélógún oṣù kẹfà, ọdún 2026 wọ́n bere ise iwadi won amo nigba to fi ma di nǹkan bí agogo kan kọjá 1:33 ọ̀sán ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹfà, ọdún 2026 won ti rowo to awon afurasi naa.
(Dókítà) Ganzallo, nínú àlàyé rẹ̀, sọ pé ní oṣù karùn-ún, ẹgbẹ́ náà ti kọ́kọ́ gbé ìgbésẹ̀ láti mú wọn, ṣùgbọ́n nítorí àìní ìmọ̀ tó tó, wọ́n dá iṣẹ́ náà dúró. Lẹ́yìn náà, ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejìlélógún oṣù kẹfà, ọdún 2026, won tun ta won lolobo nipa awon igbese awon eeyan naa pe won ma sise ni ọjọ́ Ajé àti ọjọ́ Àbámẹ́ta ti won si ri awon afurasi naa mu.
ACC Adaranijo ti ṣeto awọn osise rẹ sile ti won si dènà dewon ti won si mu won.
Bo tilejepe awon afurasi naa gbiyanju lati salo amo won mu won ni opopona Sokoto, Idogo, Ilaro, Guusu Yewa, ipinle Ogun.
Awon afurasi naa ni Gbolahan Ayobami, Omo odun metadonlogbon( 27), oniṣẹ ẹrọ grader, Adedamola Ayomide, Omo odun mokandinlogbon 29, awakọ ọkọ naa, ati Ajibose Ayobami, Omo ogun odun 20, won si tun mu awon ti won ma n lo ta Disu naa fun.
Nígbà tí wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò, àwọn afurasi náà jẹ́wọ́ pé àwọn ti ṣe ìṣe náà nígbà mẹ́ta láàrín oṣù kan. Kódà, wọ́n gbà pé àwọn ṣì ra àwọn nǹkan náà ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá.
Àwọn ohun tí wọ́n rí gbà ni; ọkọ̀ mazda pẹ̀lú àwo JJJ 913 GX, gálọ́ọ̀nù mẹ́tàdínlógún tí ó ní lítà ọgbọ̀n ti díẹ́sùlì kọ̀ọ̀kan.
Lesekese ni won ti fawon le awon eso aabo araini laabo ilu ( Nigeria Security and Civil Defence Corps Ilaro Area Command) lọ́wọ́ fun iwadi siwaju sii.



