Lobaloba

Naijiria maa dara laipe, e je ka rora maa ronu lori bi nnkan se ri bayi-Oba Olugbenle

Oba Kehinde Gbadewole Olugbenle olu ti Ilaro ati olu Oba Ile Yewa ti ro awon Omo Niajiria lati ma se Fi ironu pa ara won toripe nnkan si ma daa laipe.

Oni ojo kejila osu kokonla odun 2024 ni oba Kehinde Olugbenle soro yi nigba to n gbalejo awon akeko Ile Eko Emmanuel ti won n se ayeye aadota odun ti won da Ile Eko naa sile.
Nibe ni kabiesi ti gba awon Omo orile ede Naijiria ni imoran lati rora maa ronu lori bi ipo nnkan se le Koko bayi Tori nnkan ko ni pe roju pada.

“Mo Fe ke mo pe atun to to ye ki ijoba se ki nnkan le daa ni won n se bayi, mo ni idaniloju pe laipe nnkan ma padabo sipo”.

Kabiesi gboriyin fawon akeko naa lori awon igbese ti won gbe ati bi won se ranti lati wa se nnkan sinu ogba Ile Eko naa. Oba Olugbenle wa fi dawon loju pe Oun ma ni ki Seneto to n soju iwo-Oorun Ipinle Ogun naa wa ranwon lowo nipa Kiko Iyara ikeko  tuntun si Ile Eko.

Oba Olugbenle gboriyin fawon akeko naa o si ro won lati pese si ayeye ajodun orona to n bo lose to n bo.

Niti Ile Ile Eko naa ti won ni awon kan ti n ta mo Ile Eko naa lowo, Kabiesi je ko di mimo pe ijoba lo fa opo awon nnkan to n sele lori opo Ile Ile Eko ti awon kan ma n tun gba pada lowo awon Ile Eko to ni i .
Olugbenle ni ” O ye ki ijoba se ogba kaakiri gbogbo ibi ti Ile Ile Eko wa ati ibi ti Ile won de ni, ti ijoba ba se bee , ko ni si aye fawon ti won fe ji Ile ta lati wole wa ji Ile ta.”
Be ni oba Kehinde ro ijoba lati maa toju awon Iwe naa daadaa .
Nigba ti Pasito Jams A. Taiwo to Koko je oye Olori awon akeko lokunrin ni Ile Eko naa n dupe lowo oba Kehinde Olugbenle fun bi o se gba won lalejo, lo tun ro Kabiesi lati ba awon sise lori awon Ile Ile Eko naa ti awon kan ti gba Mo Ile Eko naa lowo bayi .
Be ni Oga agba Ile Atunse iwa Odaran to wa nilu Ilaro,ITanran J.I.(CC) (controller of Ilaro Corrections) dupe lowo awon akeko naa fun bi won se mu ebun wa fun awon ti won wa ninu ogba Atunse iwa Odaran naa.
Ogbeni Clement Babatunde Ajasa to je Oga agba Ile Eko awon Omo akanda to wa nilu Ilaro dupe lowo won fun bi won se mu ebun wa fun awon akeko to wa nile Eko awon akanda to wa nilu Ilaro . O wa ro won lati ma a ko awon Omo to ba je akanda eda wa sile Eko naa.
Be ni awon Omo Ile Eko ati oluko to wa ni Ile Eko awon akanda eda na Fi orin ati ijo da awon akeko naa lara ya. Eyi si mu inu awon akeko naa dun pelu orin kan ti oluko to je akanda eda na ko pe” latigba ti alaye ti daye ko si Omo Ile Eko Emmanuel to se ori buruku ri “. Ti eyi si dun mo awon akeko naa ninu pupo.
Abileko ……to n dari lle awon Omo alailobi to wa nilu Ilaro to  tewogba awon Ebun ti won ko wa fawon Omo alailobi je ko di mimo pe Ajo naa ti adajo Dipe Olu to ti figba kan ri dari Ile Ejo to wa nilu Ilaro tele ko to di adajo agba nipinle Ogun bayi da sile yi ti se awon Omo alailobi lanfaani lopolopo .” Omo akoko ti a Fi bere ni won ri lati ilu Sawonjo ni Ariwa Yewa, ni bayi a ni Omo to to merinla to je Omo alailobi”.
“Be ni a si ti ni Omo alailobi to n keko nipa Imo ofin ni Unilag nipinle Eko bayi

Sinkin ni Inu Abileko Dawotola to je iyawo oloogbe oloye S.A Dawotola to da Ile Eko Emanuel sile lodun 1974 n dun nigba ti Gbogbo awon akeko naa wa ni Ile won to wa ni Agbegbe modeolu nilu Ilaro .

Gbara ti awon akeko naa de Ile Abileko Dawotola to je aya oloogbe oloye S.A Dawotola ti won si fun ni Ebun ti won mu wa lati Fi dupe lowo re ni màma naa bu sekun Ayo to si n dupe lowo awon akeko naa fun bi won se wa sile oun, Be ni awon akeko naa pari Irin Ajo ojo akoko naa si Ile oloogbe ….to je oludasile Ile Eko naa .

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button