Lobaloba

Eso Asobode ranse ibanikedun si ilu Ipokia, won sapejuwe ipapoda kabiesi bi Adanu nla fun ilu re ati ipinle ogun lapapo

Igbakeji eso Asobode, kontirola O.O Afeni ti ranse ibanikedun si ilu Ipokia lori ipapoda Oba Yinusa Olaniyan ,Adelakun.

Kontirola sapejuwe kabiesi gege bi eni to n gbà àlaafia laaye, to si tun n mu ilosiwaju ba asa ati ise Ipokia ati ipinle ogun lapapo.

Bi Oba se n lo igbesi aye re lati fii mu idagbasoke ti ko legbe ba agbegbe lpokia ati ipinle ogun lapapo lo tun n sapa lati riipe àlaafia wa laarin awon olugbe lpokia ati awon eso Asobode.
Igbakeji kontirola Afeni ni: a ti padanu Baba, agbani nimoran ati Opo kan to da bi igun Ile fun wa leka bi eto aabo se Fe mule sii lenu bode ati bi eto oro aje enubode se fe ma lo bi ijoba se fe.

Kabiesi je eni to ma n sapa lati riipe ajose timotimo ati igbora eniye wa laarin awa eso Asobode ati awon olugbe lpokia .

Ko le tete rorun fun wa lati ri eni to le ma a se awon nnkan ti kabiesi n se funwa yi.

Eso Asobode eka ti idiroko tun n ba idile Oba,igbimo lobaloba ati gbogbo Omo Ipokia kedun fun ti ipapoda kabiesi.
Bee ni won si n gbadura ki olodumare wa  tu gbogbo awon ebi Oba ati gbogbo awon Omo pelu olugbe lpokia ninu ko si wa te kabiesi si afefe rere.

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button