Ni bayi ti Ile ejo ti sun eto igbejo siwaju awa agbejoro ti panupo lati mu eepo kuro laarin Alikama wa – Ogbeni Samson

Ogbeni Samson to je Alaga awon agbejoro eka ti ilaro ni ipinle Ogun lo soro yi fawon oniroyin ninu ogba ile ejo agba to wa nilu Ilaro tiise olu ile Yewa-Awori leyin ti won pari eto igbejo awon afurasi meji ti won fesun kan pe won n lo onte (Stamp) awon agbejoro kan lati Fi se iwe Ile fawon eeyan.
Ogbeni Magani Frances ati Orisaseyi Taiwo ti ẹgbẹ awon agbejoro eka ti ilaro fesun meje otooto kan ti won si mu wa siwaju adajo Ile ejo giga ti ilu ilaro, Abileko F.A Ojelade ni eto igbejo naa ko le te siwaju loni ojo kerindinlogbon osu kerin odun egbaa odun o-le merindinlogbon yi ,ti adajo si sun igbejo naa si ojo kerin osu kefa odun egbaa odun o-le merindinlogbon yi .
Esun mejeeje ti won Fi kan won lo da lori bi won se lo Ami idanimo iyen onte (Stamp) awon agbejoro meta yi: Oluwaseyi Emmanuel, Akinwande. R. Ajayi ati Akintunde .O. Olurotimi, lati Fi se iwe Ile fawon eeyan, ti eyi si tako iwe ofin orileede Naijiria sekision 516, 465, 419,484 ti eto ijiya re si wa ni abala 467 ti iwe ofin odun 2006.

Botilejepe awon ti won fesun mejeeje naa kan ni awon ko jebi, amo Adajo F.A Ojelade ti sun igbejo naa si ojo kerin osu kefa odun egbaa odun ole merindinlogbon yi. O si pase pe ki won da awon afurasi naa pada si ogba ewon to wa nilu ilaro.
Ogbeni Samson to je Alaga awon agbejoro je ko di mimo pe ẹgbẹ awon ti setan lati ba awon afurasi naa se ejo ki awon si Fi won jofin ko le je apeere fun iru awon ti won ba n se iru nnkan bee.
Be ni ogbeni Samson to je Alaga awon agbejoro ni ni Ilaroje to ko di mimo fawon oniroyin pe awon ti setan lati yo eepo kuro laarin Alikama awon agbejoro “ofin orile ede wa ko fayegba eni ti ko ba lo sile eko agbejoro lati maa pe arare ni agbejoro, ti enikeni ba fe ma sise agbejoro o gbodo Koko lo sile eko awon agbejoro”.
” Iwa yi si wopo laarin awon kan ti a n pe ni leta writer” Awon ni won maa n ba awon eeyan se iwe ile ati opo awon iwe laarin awon meji ti won ba ta Ile tabi Ile funrawon ti eyi ko si ba ofin orileede Naijiria mu”.
” Kiki eni to ba lo sile eko agbejoro nikan lo ni anfaani lati ma bawon eeyan se iwe ile tabi iwe ile “.
Idi niyi ti a se mu awon afurasi ti won n lo ami idanimo awa agbejoro ti a n pe ni stampu sori awon iwe ile ti won ma n ba awon eeyan se, ti a si maa fi won jofin kawon to ban se iru iwa bee Le jawo ninu re.
Ogbeni Hakeemu Dawood ti won yan gege bi olopa kogberegbe fawon egbe
agbejoro nile ejo Ilaro dupe lowo awon akegbe re to ku fun atileyin won latigba ti won ti yan oun si ipo naa .
“Atileyin won loje ka ri awon meji yi mu, mo si fi n dayin loju pe gbogbo awon to ku ti won ma n pe arawon ni agbejoro lai se agbejoro ni a ma mu. Tori a Fe mu epo kuro laarin Alikama awa agbejoro bi Alaga mi se so.
“Bi mo se duro siwaju yin yi mi o mo ibi to sitampu mi ti de Tori se lawon obayeje yi kan tie ma n lo sitampu wa lati Fi sise gege bi ojulowo agbejoro “.
Ogbeni Orisadare to je akowe egbe awon agbejoro eka ti Ilaro naa tun ro awon araalu lati mase ma lo si odo awon ti kii se agbejoro ti won ba fe se iwe ile tabi iwe ile won.
” Akoba to tun wa nibe nipe won o ni se ojulowo iwe fun won gbarokudu ni won ma se fun won” .
Idi niyen ti a se n ro awon araalu ki won ma wa ojulowo agbejoro gbe ise won fun ti won ba Fe se iwe Ile tabi iwe Ile .