Ijoba fofinde kiko iresi ile okeere wole si Naijiria,tori kii se ile Adulawo ni won ti gbin in – Shuaibu Muhammed

Oga agba ajo eso asobode nipinle ogun, kontirola Mohammed Shuaib, ti so idi ti ijoba orileede Naijiria ko se gba ki won ma ko iresi wole lati orileede Olominira Benin.
Kontirola ni, ljoba Naijiria ko gba ki won ma ko awon iresi naa wole tori pe kiise orileede olominira Benin ni won ti n gbin awon iresi naa.
Shuaibu soro yi nibi ipade ajoro kan ti won pe akori re ni, igbelarugẹ aṣa ati iṣe fun idagbasoke eto oro aje eleekerin iru re to waye lojo kejila osu keji odun egbaa odun o-le marunlelogun yi ni ofisi re to wa ni idiroko.
Ipade naa ti ogbeni Borny to je asoju laarin orileede olominira Benin sagbateru re pelu ifowopamo ajo eso asobode ati awon olugbe agbegbe naa ni o da le lori awon ona ti asa,ise ati ise ona tun le gba mu ilosiwaju ba eto oro aje orileede Naijiria, ile olominira Benin ati gbogbo ile Adulawo lapapo
Muhammed te siwaju sii pe to ba je pe orileede olominira Benin tabi ile Adulawo mii to wa laarin ajo Ecowas ni won ti n gbin awon iresi naa ni oseese ki ijoba Naijiria gba ki awon eeyan ma ko wole ni ketiketi latari ajose to wa laarin ile Adulawo.
Akọle nnkan ti wọn jiroro le lori lọdun yii ni ‘Ẹnu-Bode, ki lo jẹ ati ki lo de to fi ṣe pataki’ Nibi tọrọ kan lorileede Naijiria ati Benin, ti jọ jiroro lori ipa ti okoowo n ko ninu idagbasoke aṣa.
Ọga agba asọbode naa ṣakiyesi pe okoowo ki i ṣe nipa ọja nikan bi ko ṣe pe o tun jẹ ki ajọṣepọ to danmọran wa laarin orileede, bẹẹ lo ni o tun mu agbọye wa, to si n jẹ ki alaafia jọba pẹlu.

Nigba to n sọrọ nibi ayẹyẹ ọhun, Dokita Bonny Abisogun Botoku, to jẹ ọga fawọn to ṣeto naa sọ pe o gboriyin fawọn aṣọbode atawọn alabojuto ẹnu aala lori ọna ti wọn gba lati jẹ ki aabo to peye wa lori ọrọ okoowo lawọn agbegbe naa.
O ṣapejuwe ẹnubode gẹgẹ bi ibi towo n gba wọle, to n pese iṣẹ ati ibi ọja ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin. Lara awọn nnkan to waye lọjọ naa ni idanilẹkọọ to waye nibi ti igbakeji ọga kọsitọọmu C Amaweh, ti sọ nipa ipenija ti wọn koju ati ọna abayọ bẹẹ lo tun mẹnuba ọna igbooro laye ode oni.



