Inu mi ko dun bi awon to sejoba siwaju mi ko se mu idagbasoke ba agbegbe yi….inu mi dun bi won se yi ayeye oronna si oni nitori mi-Gomina Dapo Abiodun

Gomina Dapo Abiodun ti fi aidunnu re han si bi awon to ti sejoba siwaju re nipinle Ogun ko se fi bee mu idagbasoke to loorin ba Iwo-oorun lpinle ogun, ti won si pa agbegbe naa ti.
Gomina soro yi lojo kini osu kejila odun 2024 nibi ayeye asekagba ajodun oronna.O tesiwaju pe” idi niyi ti mo se pinnu lati ma a se opo nnkan si agbegbe yi ki iyato le wa”.
Leyin ti mo se opopona ilaro si Owode tan, ti mo si si apa akoko ninu opopona Atan-Lusada-Agbara a ti n se apa keji lo bayi”.
Ise idagbasoke agbegbe yi n mumu laya mi tori ile ise to wa ni iwo- oorun ipinle Ogun yi ju 500 lo.
Be ni agbegbe yi ni ile ise simenti to tobi ju lo nile Adulawo wa .Be ni Ibi ni ounje ti n wole si orile ede Naijiria ju.
Gomina Dapo Abiodun wa seleri pe oun ko ni kere lati maa mu idagbasoke ba lwo-oorun lpinle Ogun.
Gomina gboriyin fun Oba kehinde Gbadewole Olugbenle ati awon komiti ayeye odun Oorona fun bi won se mu atunto ba ayeye naa ko le seese fun gomina lati wa sibi ayeye naa.
” Inu mi dun nigba ti won ni won ti yi ojo ayeye asepari oorona si oni ojo kini osu kejila. Mo mo pe ogbon ojo osu kokonla ti won fi si ti ha fun mi, tori ma wa ni Iperu nibi ayeye ajodun odunAkesan amo nigba ti mo gbo pe won ti yi ayeye yi si oni ojo kini osu kejila odun egbaa odun ole merinlelogun yi ki n le wa nibe, o jomi loju gidi gan.”
” Nigba ti mo si ri Seneto Yayi ati awon Seneto to ku ti won wa ba mi se ayeye Akesan ni lperu mo ri i pe emi naa gbodo fi aye sile ki n wa sibi loni”.
” Mo dupe lowo Oba olugbenle ati Seneto Olamilekan Adeola fun bi won se n mu idagbasoke ba iwo- oorun lpinle ogun , E ma a rii pe awon ijoba to koja ko fi be mu idagbasoke ba agbegbe yi bii tiwa .
Oba Kehinde Gbadewole Olugbenle olu ti ilaro ati olori Oba nile Yewa wa dupe lowo gomina ati gbogbo awon seneto ati alejo to wa sibi ayeye asepari oorona naa ,o si sadura fun gbogbo won.
Lara awon ti won tun wa nibi ayeye ajodun oronna naa ni : Igbakeji gomina lpinle ogun, Abileko onimoero Noimort Salako Oyedele; Seneto Olamilekan Adetola to n soju iwo-oorun lpinle ogun nile igbimo Asofin apapo labuja;
Onorebu. Abiodun Akinlade; ; Deputy Senate President, Senator Barau Jibrin; oga agba awon olopa lorile ede Naijiria Egbetokun;
Seneto, Opeyemi Bamidele; Minister fun eto ilera labele, Dokita Isiaq Salako.
Abenugan ile igbimo asofin ipinle ogun Onorebu Elemide ati awon onorebu toku pelu awon closely mii nipinle Ogun.
Oba Amusa Adetunji Dosumu Elebute ti ilu Ebute lgbooro pelu awon loba loba nile Yewa naa wa nibe pelu.
Bee ni Alaaji Ibrahim Dende Egungbohun to je alase ati oludari ile itura IBD pe awon eeyan jankan jankan ati olorin wa lati orile ede olominira Benni ati Togo sibi ayeye asekagba naa to waye ninu ogba
Empire Pavilion, Ilaro Ogun State.

Be ni Alaaji Taiwo Hassan ti opo mo si Ogogo se eto bi ijo Gelede, Egungun ati asa ibile ilaro mii se wa sibe lati wa da awon eeyan laraya ki olorin fuji ni K1 to wa fi orin fuji kadi eto naa nile.



