Kontirola Otunla seleri ajosepo to dan moran pelu awon olokoowo to wa lenu bode Idiroko.

Ọga agba aṣọbode ipin akoko nipinlẹ Ogun, kontirola G A Ọtunla ti mu un da awọn to n sowo lenu bode ipinle ogun loju pe ọrọ aje yoo tubọ tẹsiwaju gan an ladiko ti oun wa gege bi oga agba ajo naa nipinle Ogun.
Otunla yi lasiko ipade to se pelu awon olokoowo to wa lenu bode orile ede Naijiria ati ti awon to wa ni orile ede olominira Benni lojo kerindinlogun osu karun odu 2025.
Nibẹ ni wọn ti jọ jiroro nipa bi ohun gbogbo yoo ṣe di irọrun. Awọn aṣoju lati orileede Benin to wa nibi ipade na so ojuwoye won nipa bi nnkan se ma lo daadaa laarin orile ede Naijiria ati orile olominira Benni.
Kontirola ṣalaye siwaju pe pataki ni eto aabo jẹ, idi si niyii tawọn ko ṣe le fọwọ rọ sẹyin nibi ijiroro wọn ti wọn si fẹnu ko lori bi wọn yoo ṣe ṣiṣẹ pọ le lori tawọn orileede mejeeji yoo si maa ṣiṣẹ wọn pẹlu ifọkanbalẹ.
Atẹjade ipade ọhun eyi ti agbẹnusọ awọn aṣọbode nipinlẹ Ogun, Chado Zakari, fi sita tun ṣalaye pe dandan ni eto ọrọ aje lorileede yii ati ti Benin to mule ti wọn, idi si niyi tawọn fi gbọdọ maa forikori lati maa wa ọna abayp sawọn ohun to ba fẹẹ jẹ ipenija.
Ọtunla waa dupẹ lọwọ awọn ọmọọṣẹ lori ifarajin ti wọn ni lẹnu iṣẹ ti wọn yan laayo ọhun bẹẹ lo tun fẹmi imoore han si ọga wọn pata lorileede yii, Bahir Adewale Adeniyi fawọn atilẹyin ti wọn ri gba loorekoore.




