ÌṢÒWÒ

Kontirola Muhammed Shuaibu gba Moto,lresi ati awon eru fayawo to po laarin ose kan….o si kilo fawon onifayawo lati fi ipinle ogun sile.

Kontirola Muhammed Shuaibu to Bere ise gege bi oga agba ajo eso asobode nipinle Ogun ni nnkan bi ose kan seyin ti mu die lara awon ileri to se nigba to Bere ise gege bi oga agba awon asobode ni eka akoko to wa ni ipinle Ogun.
Oni ojo kokondinlogun osu kejila odun 2024 yi ni oga agba naa fi awon eru ati opo nnkan to gba lowo awon onifayawo han awon akoroyin ni ofisi re to wa ni idiroko.

Lara awon nnkan ti won gba lowo awon onifayawo naa ni ; Oko Tokunbo Toyota Highlander 2012.

Apo baagi lresi oni aadota kilo to je  2,169


Idipo igbo egberunkan ogorun marun ati eyo mejidinlogbon
Idipo aso aloku mokanlelogun ati saaki meji
Alokutaya 166


Paali Bata aloku
Epo Bentiro 250 oni lita marundinlogbon


Aropo owo ori awon eru naa je #229.1m.
Kontiro Shuaibu je ko di mimo pe die ni awon nnkan ti awon gba yi ma je lara awon nnkan tawon fe maa gba lowo awon onifayawo bayi.
O je ko di mimo pe oun ti se awon eto kan to maa je ko rorun fawon osise oun lati ma fi sinkun ofin mu awon to ba n sise fayawo nibikibi to wu ki won gba.
O wa dupe lowo awon osise re ati awon eso alaabo toku fun atileyin ti won se fawon kawon to le ri awon onifayawo naa mu.
Be lo dupe lowo oga agba ajo naa lorile ede Naijiria, ogbeni Bashir Adewale Adeniyi fun atileyin re

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button