ÈTÒ ÀÀBÒ

Ijoba mi ko ni Faye gbà awon ajinigbe nipinle Ogun-Gomina Dapo Abiodun

Gomina Ipinle Ogun, Omoba Dapo Abiodun, ti Fi da awon olugbe ipinle ogun loju  pe ijoba oun ko ni Faye gbà awon esin o koku ajinigbe lati ribi ha si lati ma sise ibi won ni ipinle Ogun.

Gomina Abiodun ṣe ìkéde náà nígbà ìpàdé (All Progressives Congress) to wáyé ní Ile Aare to wa ni, Ibara nilu Abeokuta tiise olu ilu ipinle Ogun.

Nígbà tí ó ń ṣàpèjúwe bi awon ajinigbe se ń pọ̀ sí i ní gbogbo orílẹ̀-èdè náà gẹ́gẹ́ bí ohun tó ń bani nínú jẹ́. Gomina fi dá àwọn ará ìlú lójú pé ìjọba oun ti n gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti dènà àwọn ọ̀daràn ajinigbe ki won ma ba raye wole si ipinle naa .

“A ti n gbe igbese lati maa lo eto imo-ero lati maa Fi daabobo ẹmi ati dukia awọn eeyan wa. A ko ni duro de ẹnikẹni lati wa kọlù wa,” Abiodun sọ bee.

” A tún fi n da awon eeyan wa loju pe ìjọba wa maa rí pe eto ààbò maa duro digbi jakejado ipinle wa be ni ajosepo to Dan moran ma wa laarin awon eleto aabo ati àwọn araalu”.

Gomina ni; ‘awon ile-iwe ati awon ile-eko giga wa je awon ibi to munmun laya wa lati riipe eto abo re duro digbi, Tori a ko Fe ki nnkan buruku sele si awon omowa,Tori awon ni ogo ojo ola wa.’

Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, ìjọba ti seto lati  mú kí eto aabo tunbo nipon sí i ní àyíká àwọn ilé ìwé nípa jije ki awon eleto aabo tunbo po sii ju ti tele lo lawon Ile eko wa a si ti tun n lo imọ̀ ẹ̀rọ ìgbàlódé sí àwọn agbègbè Ile eko wa.

Ó ní àwọn ígbese yi la gbe  láti dènà àwọn ìwà ọ̀daràn àti láti rí i dájú pé àwọn ilé-ẹ̀kọ́ wà ní ààbò àti àyíká tí ó dára fún ẹ̀kọ́.

Gomina wa dupe lowo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ APC ní Ìpínlẹ̀ Ogun fun bi eto idibo abele ẹgbẹ Oselu naa se lo laisi wahala ti eyi si Fi han pe isokan ati àlaafia wa laarin Omo ẹgbẹ Oselu APC nipinle Ogun.

“Ìgbìmọ̀ wa jẹ́ èyí tí ó gba gbogbo ènìyàn láyè, tí ó ṣe kedere, tí ó sì jẹ́ òdodo. A jókòó, a jíròrò, a sì yan àwọn olùdíje wa láìsí ìbínú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ń díje, ẹnìkan ṣoṣo ló jawe olubori. A dupe lowo awon ti won finufido Fi ipo won sile fawon mii ki ilosiwaju le ba egbe.

Ṣáájú, Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní Ogun, Olórí Yemi Sanusi, yin àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú fún ìwà rere wọn nígbà ìdìbò àkọ́kọ́ àti lẹ́yìn ìdìbò, ó sì sọ pé wọ́n pe ìpàdé náà láti mú kí àwọn ìṣètò àti ìgbìyànjú láti mú kí ìdìbò gbogbogbòò ọdún 2027 lágbára sí i.

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button