Kontirola Afeni gbalejo kọmiṣanna Olopa Bode Ojajuni, won Panupo lati mu eto aabo pinpin lenu bode ipinle ogun.

Kontirola eṣọ aṣọbode nipinlẹ Ogun, Ọladapọ Afẹni ti ṣeleri fun Oga olopa pe ajọṣepọ to danmọran maa wa laarin awọn pẹlu awọn ileeṣẹ alaabo yooku lati rii pe abo to peye wa lawọn ẹnu bode orileede Naijiria.
Afeni sọrọ yi nigba to n gbalejo kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Bọde Ọjajuni, ni ofisi re to wa ni idiroko .
O dupe lọwọ ajo eleto aabo lori bi won se je ki igbọraẹniye ati ifọwọsowọpọ maa wa laarin wọn, eyi to jẹ ki wọn maa ṣaṣeyọri lori awọn iṣẹ ti wọn n ṣe lati gbogun ti awon onifayawọ.
Kontirola je ko da Oga olopa loju pe bi awon osise won se fowosowopo pelu awon lo tunbo je ko rorun fawon ẹṣọ aṣọbode lati pa owo wọle sapo ijoba Apapo, bẹẹ lo si tun sọro nipa afojusun wọn lori eto ọrọ aje, okoowo ati aabo, eyi to ti nipa rere fawọn araalu, eyi to ni o ti mu idagbasoke rere wa nipasẹ ifọwọsowọpọ pẹlu awọn eleto abo yooku.
Afẹni tun menuba bi awọn ati orileeede Benin tun ṣe jọ n ṣiṣẹ pọ lẹnu aala to pa orileede Benin ati Naijiria pọ, to tun ni ara aṣeyọri ti ko lẹgbẹ ni.
Afeni ni aimoye sekipoiti lo wa ni opopona to wa ni idiroko nigba ti oun de amo oun din ku ko le rorun fawon onisowo to n sowo lati orileede Naijiria si orileede Benin ti igbese naa si ti je ki Owo sise tunbo rorun fawon eeyan lagbegbe naa.
O waa ṣeleri pe gbogbo ọna lawọn yoo maa gba gẹgẹ bi iṣẹ wọn lati pese abo fawọn araalu, ki awọn onifayawọ si rin jinna rere nipinlẹ Ogun.
Kọmiṣanna ọlọpaa Bọde Ọjajuni naa gboriyin fun ọga agba eso aṣọbode lori ipa to ti ko lẹnu igba to ti gba ipo leka aabo, okoowo ati ọrọ aje.
Bẹẹ lo tun mẹnuba bi alaafia ṣejọba ni idiroko ti gbogbo okoowo n lọ nirọwọ rọsẹ.Oun naa wa ṣeleri pe ajọṣepọ to wa laarin awọn mejeeji yoo tubọ maa tẹsiwaju.

Be ni awon Oga mejeeji naa gbe awoodu funrawon lati fi emi imoore han fun bi olukuluku se n se aseyori leka ise aabo. Bi Oga olopa se n fun kontirola Afeni ni awoodu ni kọntirola Afeni naa n fi awoodu da kọmiṣanna Olopa Bode Ojajuni lola .



