LÁGBÓ-ÌDÁRAYÁ

Ìdíje bọ́ọ̀lù AFENI CUP 2026 ni a gbe kale láti fi se ilaniloye fawon akeko nipa ewu to wa ninu ise fayawo-Kontirola Afeni

Ajo eso Asobode eka akoko nipinle ogun ti sagbateru eto idije boolu afesegba kan ti won pe ni Afeni Cup 2026 laarin awon akeko to wa ni agbegbe Idiroko ni ijoba Ibile Ipokia.

​idije naa ni ajo eso Asobode ati Ile eko (Jonnyyeko College of Health Science and Technology), seto re lati fi se ilani loye fawon akeko ti won wa ni agbegbe enubode lati mo ewu to wa ninu ise fayawo ati akoba to maa n se fun ojo ola awon odo.

Nibi eto iside boolu afesegba naa ni Igbákejì Olùdarí Àgbà awon eso Asobode Oladapo Afeni , ti  sọ pé awon gbe eto naa kale kawon le lo o lati Fi se ilaniloye fawon akeko ki won le ri ewu to wa ninu ise fayawo ati idi to se ye ki won yera fun un. Be lo tun tesiwaju pe awon tun gbe eto naa kale ki won le mo pe awon le se oriire lai se ise fayawo rara.

Afeni tẹnu mọ́ ọn pé awon nigbagbo pe ti won ba mo pe awon le gbà boolu la nigba ti won si wa ni kekere o maa ranwon lowo lati Fi se ojusun won ki won ma si ya sidi ise ti ko bofin mu rara.

Idije naa ni awọn ẹgbẹ agbaboolu mejila (12) ninu ti aropo gbogbo awon akeko ti won maa kopa nibe si to ogorun.

Lesekese ti idije naa ti bere ni awon oluko ati akeko pelu ẹgbẹ awon Odo ati awon Agbalagba ti won wa ni agbegbe naa ti n kan saara si Oga agba awon Asobode fun eto boolu ti won gbe kale naa.

Àwọn ẹ̀bùn ńlá, títí kan àwọn ohun èlò ẹ̀kọ́ àti owó, lo ti wa nile fún àwọn ilé-ẹ̀kọ́ tó ba borí ninu idije naa .

Idije naa bẹrẹ ni ọjọ kẹtala oṣu Keje ọdun 2026 ni Ile-iwe Grammar Iko Gate, Idiroko, o si ma pari ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu Keje ọdun 2026.

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button