Ìyáwo Ààrẹ Tinubu,se ifilole ibudo ounje fawon mekunnu, o tun fun Ọmọ odun mejila to n yaworan ni ₦10 Milionu

Seneto Oluremi Tinubu to je Iyawo Aare orileede Naijiria ti fun Omo odun mejila to ya Aworan iyawo Aare sinu patako kan lasiko to wa si Ile gbigbe ati Osibitu ti won si se ifilole eto ounje fawon mekunnu Guusu Naijiria ni ilu Abeokuta tiise olu ilu ipinle ogun.
Ojo kejidinlogun osu kejo odun Egbaa odun o-le merindinlogbon yi ni isele naa sele lasiko ifilole South West Zonal National Community Food Bank Programme, èyí tí ó wáyé ní Cultural Centre, nilu Abeokuta.
Eto ounje fawon mekunnu yi ni won ni awon ologun ati awon Omo ojo kan si bii odun mefa a maa janfaani re, ki igbesi aye won le tunbo nitumo sii.
Nígbà tí Ìyáwo Ààrẹ ń sọ̀rọ̀, ni omodekunrin naa gbe Aworan naa soke laarin awon eeyan . Nigba ti Aya Aare soro tan lo ba pe omodekunrin naa sita, nibe ni Omo naa ti so pe oun Fe ki iyawo Aare ran oun lowo ki oun le ni studio ti won ti oun ma ko awon Aworan ti oun ti ya si.
Be ni iyawo Aare ni “mo ti ri e bi o se n gbe Aworan mi soke nigba ti mo ti wole sinu gbogan yi, mo Fe ko mo pe AI le ya nnkan to ya yi, amo ma seto bi o se ma pari eko re ma si fun e ni million mewa naira”.
“Mo ti rí ọ. Mo rí i pé o dúró tí o gbe àwòrán mi soke. Amo Joo jẹ́ kí n parí ọ̀rọ̀ mi. Jọ̀wọ́ jókòó.”
Nigba ti iyawo Aare soro tan lo wa pe Omo naa ati Gomina ipinle ogun, Omooba Dapo Abiodun pelu Iyawo re Bamidele Abiodun sori pepele Lẹ́yìn náà, ó pe ọmọ náà sí pèpẹ̀lẹ́, ó sì fún un ní gbohungbohun kí ó lè sọ̀rọ̀.
Ọmọ ọdún mejila 12 náà, Omo naa ni akẹ́kọ̀ọ́ JSS 2 ni oun, be lo salaye pe oun ti ni àkójọpọ̀ àwọn àwòrán ti oun Fi pencil ya to ju igba [200] lọ, àti pé óun fẹ́ ki Aya aare ran oun lowo lati ni ibi ti oun Fe ma ko awon Aworan naa si iyen gallery tirẹ̀.
Iyawo Aare orileede Naijiria ba so fun Omo naa pe “Ó yẹ kí o kọ́kọ́ lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ kí o sì parí ẹ̀kọ́ rẹ. Ohun kan gbọ́dọ̀ tẹ̀lé òmíràn. Ma Koko Fi milionu mewa ₦10 milionu ran e lowo”.
Inu Omo kunrin naa dun o si dupe lowo iyawo aare.




