ÌRÒYÌN

Kontirola Muhammed Shuaibu ro awon ofisa ti won gba igbega lati maa sise kara ki won si je olooto lenu ise won 

Oni ojo kejidinlogbon osu kini odun egbaa odun o-le marunlelogun yi ti Kontirola Shuaibu Muhammed n dekoreeti awon aadota ole osise asobode ti won gba lgbega ninu awon asobode eka ti ldiroko lpinle ogun lo so oro naa fawon osie asobode ohun.

Awon aadota o le naa ni won wa lara awon ti won kopa ninu idan won ti ajo eso asobode se fawon osise asobode laipe yi .

Shuaibu ro awon ofisa ti won gba igbega lati maa sise kara ki won si je olooto lenu ise won .

Awon merindinlogun ti won gba igbega sipo Chief Superintendent ti asobode ti awon meji si gba igbega sipo (Superintendent of Customs) pelu awon ti won tun gba igbega sawon ipo mii .
Ninu oro iyanju re sawon ti won sese gba igbega ninu ise asobode, ni oga agba ajo naa ni eka akoko nipinle Ogun, Kontirola Shuaibu Muhammed ti je ko ye won pe ise asekara ati jije ti won je olooto lo je ki won de ipo ti won de naa .

O wa ro won lati maa ba ise naa lo ki won si ma fi isotito inu see.

Be lo ro awon ti won ko tii gba igbega lenu ise lati mase soretinu, o wa fi dawonloju pe owo olorun ni igbega ti ma n wa o si daju pe o ma se tiwon naa ti asiko ba to loju re.

”  Niti eyin ti e gba igbega lati Ipokan si omiran loni, Mo fe ki e mo pe orisirisi ipenija le ma ba pade bee se gba igbega yi amo e ko gbodo jaya tori e gbodo riipe e n sise naa gege bo se to ati bo se ye.”
Nigba ti Okorn Ogar to je okon lara awon osise asobode to gba igbega sipo (Superintendent of Customs) n dupe loruko awon to ku re lowo manejimenti asobode ati Kontirola awon eso asobode lorile ede Naijiria fun ise ribiribi ti won se lati je ki eto igbega naa waye fawon osise asobode lasikoyi.
Ogar dupe lowo won gan o si fi da awon eka eso asobode loju loruko pe gbogbo awon ti awon gba igbega lawon ma sapa lati sise ni ibamu pelu ofin ati ilana ti won fi da ise asobode sile lorile ede Naijiria.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button