Lobaloba

Ori ile Yewa ni Olorunda wa kiise ile Egba, ki awon Egba ma yan oba le wa lori- Awon olugbe Olorunda

 

Awon omo ilu ati olugbe Abule Olorunda ni ijoba ibile Ariwa Abeokuta ni ipinle Ogun ti ke gbajare sita lori pe awon ko faramo bi awon kan se n gbiyanju lati yan ogbeni Segun Ogunsola Philip le awon lori gege bi Orunda ti Abule Olorunda .
Awon olugbe agbegbe yi lo yabo olu ile awon akoroyin to wa ni oke ilewo nilu Abeokuta lojo kejila osu keta odun egbaa odun o-le marunlelogun yi, ti won si n ke tantan pe awon ko gba ki won yan Ogunsola le awon lori lati ma dari Abule awon tori omo Gbagura ni kiise omo Abule Olorunda.
Lara awon nnkan ti awon olufehonuhan naa ko Sara awon nnkan ti won gbe dani ni: “Olorunda ko ni Ogunsola ti wa” “Baale ko ni Ogunsola Segun, won ko si gbodo fun un ni agbega nipo Baale rara”.” A ti ni Baale to n sakoso Olorunda” e mase da Ogun sile ni Abule Olorunda “, O ye ki ijoba bere si ni feti si awon otosi ati awon ti ko ni oolugbeja rara”.
Oloye Johnson Oguntade to je akowe keesan orile Abule Olorunda to ba awon akoroyin soro lasiko ehonu naa sope awon olugbe Abule Olorunda ko faramo igbese ti Ijoba n gbe lati yan oloye Ogunsola le won lori gege bi oba ni Abule naa tori kiise omo agbegbe naa ni.

Atipe awon ko ni gba ki eni ti kii se omo ilu awon ma wa dari ilu awon.
O koko dupe lowo Gomina ipinle Ogun omooba Dapo Abiodun fun ise ribiribi ti gomina n se lati mu idagbasoke ba ipinle Ogun ati bi gomina se mu oro aabo ilu ati dukia lokunkundun .
” o ni,” a wa sibi loni toripe a fe ki gomina mo opo nnkan to n sele ni ilu Olorunda ni. Looto Abe ijoba ibile Ariwa Abeokuta ni won pin Ilu Olorunda si amo a fe ki gomina mo loni pe ori ile Yewa ni ilu olorunda wa kiise ori ile Abeokuta ti won pin in si”. ” Be ni a fe ki gomina mo pe Baale la fi je ni Olorunda kiii se Oba.”
” Oloye Ashamu Adegbola Agbomabiwon ni eni ti ilu ni ko ma dari wa gege bii Baale Olorunda, tori Olorunda ko si labe Gbagura rara ori ile Yewa lo wa”.
” A n fi asiko yi pe ijoba ipinle Ogun lati dasi oro naa tori a n gbo oro kan pe awon kan ti n gbimopo lati yan ogbenikan ti won n pe ni Ogunsola Philip gege bi Oba le wa lori . Ogunsola kiise omo bibi Olorunda, a ko fe ki oro naa da Ogun sile nilu la se n ke si ijoba ipinle Ogun, Komisanna to n ri si oro oye jije ati oro ijoba ibile ,Onorebu. Ganiu Hamzat ati Adajo ,Onorebu Oluwashina Ogungbade ati Komisanna olopa Lanre Ogunlowo pelu oga agba Amotekun ,Brig,Gen.Alade Adedigba (rtd) ni ipinle Ogun pe ki won bawa da si oro yi tori a ko fe Ogun ni ilu Olorunda”.
Be ni ogbeni Oyeyemi Abogunrin to je Olori Odo Keesan orile naa je ko di mimo pe Ogunsola kii se Baale atipe ki ijoba ma fun ni Igbega lati Ipo Baale sipo Oba ,tori Oloye Ashamu Adegbola Agbomabiwon to wa labe idari Oba Omola ti Imala Yewa ni o n pase gege bi Baale ibe.
O ni ” Ogunsola Segun kiise Baale ,ko si le di oba rara .Olorunda ko si lori ile awon Egba ori ile Yewa lo wa.Ogunsola Philip kiise omo bibi Olorunda omo Egba tun ni be ni ori ile Yewa ni Olorunda wa kiise ile Egba.
Tori awon idi yi ni ko se le joba tabi pase de ori ile Olorunda to wa lori ile Yewa.A ko fe ki oro yi di Ogun la se n fe ki ijoba ipinle Ogun wa ba wa da sii.
Komuredi Abegunrin tun fi kun un pe lati Odun 2014 ni ejo kan ti wa niwaju adajo Majekodunmi ti ejo naa si dale awon oro ti a n fa yi, ni iyara igbejo kerin ni kootu to wa ni Oke-Mosan nilu Abeokuta.
O wa n ro ijoba ipinle Ogun loruko awon olugbe ati omo Olorunda pe ki omooba Dapo Abiodun jowo ba awon da si oro naa ki won si gbe eto fun eni to to si lai segbe.

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button