Ẹgbẹ Legacy brothers IJOUN ṣe ìpàdé won dori ipinu bi ilosiwaju se fe ba ilu ijoun ati Ile Yewa lapapo.

Ẹgbẹ Legacy Brothers ijoun je okon gboogi ninu awon ẹgbẹ to wa Nile ketu, to si n sise Lori bi ilosiwaju se maa ba ilu ijoun, Ile ketu,Ile Yewa ati ipinle ogun pelu orileede Naijiria lapapo.
Eyi lo fa a ti awon Omo ẹgbẹ naa labe Alaga komuredi Moses iroko se ma n padepo loorekoore lati maa soro Lori bi ilosiwaju se fe ma ba ẹgbẹ naa.
Ipade won to waye Nile itura Dolad to wa nilu ilaro ni won ti jiroro awon nnkan to ma mu ilosiwaju ati idagbasoke ba ilu ijoun ati agbegbe re.
Ninu oro ti Aare ẹgbẹ (Yewa Youth Association) komuredi Isikalu Alamu to je Aare ẹgbẹ naa tele fi soju Opo Facebook re leyin ti ipade naa pari lo ti sapejuwe ipade naa bi eyi to maa mu ilosiwaju ba ilu ijoun ati agbegbe re lapapo.
Isikalu ni “Àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Legacy Brothers, Ijoun níbi ìpàdé wa tó yọrí sí rere tí a ṣe ní Ile itura Dolad, ni ilu Ilaro,Ìpínlẹ̀ Ogun, gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Aṣáájú fún ẹgbẹ́ náà àti Ààrẹ Ẹgbẹ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Yewa (Yewa Youth Association)”.inu mi dun pe mo wa nibe.
Inu ipade naa ni won ti soro Lori bi ìdàgbàsókè se Fe ba ọrọ̀ ajé àwùjọ wa, on tun soro Lori ero eko ati eto aabo ni ilu ijoun ati agbegbe re se maa lágbára sí i.
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà tun jíròrò Lori awon ona mii ti idagbasoke ma gba ba agbègbè naaati Ile Yewa pelu ipinle ogun ati orileede Naijiria lapapo.
Ààrẹ ẹgbẹ́ Legacy Brothers, Ijoun, komuredi Iroko Moses, dupe lowo gbogbo àwọn ọmọ ẹgbẹ́ fún atìlẹ́yìn ati ìfarajìn, wọn sí ìlọsíwájú ẹgbẹ́ náà. Ó tún rọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ láti je ki isokan to wa ninu ẹgbẹ naa maa tesiwaju tori iyen nikan lo le mu ẹgbẹ naa saseyori.
Leyin naa ni won pari ipade naa pelu adura ti won si ya foto àwọn ọmọ ẹgbẹ́, èyí tí ó ṣàfihàn ìṣọ̀kan, ìṣọ̀kan, àti ìfaramọ́ àpapọ̀ sí ìdàgbàsókè Ijoun àti Yewa Land.



