ÒṢÈLÚ

Gomina Dapo Abiodun to fa Seneto Adeola le awon lobaloba ijebu lowo

Gomina Ipinle Ogun, Omooba Dapo Abiodun, ti fi oludije gomina (All Progressives Congress) Seneto Solomon Olamilekan Adeola, ati igbakeji re Abileko Kudirat Abiodun Adegunwa-Balogun, han awon lobaloba ila oorun ipinle ogun .

Ojo kewa osu keje odun egbaa odun ole merindinlogbon yi tii se ojo eti ni Gomina lo Fi Adeola ati Igbakeji re han awon lobaloba naa ní Ààfin Awujale ní Ijebu-Ode.

Nígbà tí ó ń bá àwọn ọba ila oorun ipinle ogun sọ̀rọ̀, Gómìnà Abiodun sọ pé yíyàn tí òun ati ẹgbẹ Oselu APC yàn Sẹ́nétọ̀ Adeola gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó fẹ́ gbàpò lowo oun ni pe oun mo pe oun nikan lo ni ogbon ati oye to Kun to lati pari Opo awon ise idagbasoke ti oun n se lo lowo, idi miran nipe Seneto Adeola wa lati Iwo-oorun ipinle ogun ti awon to wa nibe ko si tii se ijoba ri lati aadota odun ti won ti da ipinle ogun sile.

“kiise pe mo fe lo fun igba keta ni mo se lo mu oludije lati Iwo-oorun ipinle ogun amo mo rii pe ti a ba ni ka pin in re laare, o ye ki awon to wa lati ibe naa de ipo Gomina tori ko dara bi won ko se tii de ipo Gomina lati aadota odun seyin”.

” Mo si n fi da yin loju pe eni ti eyin lobaloba maa gbadun ni, tori o ti wa ninu oselu tipe eni ti oro awon eeyan si n je logun ni, Mo ti ri gbogbo awọn iwa ti mo n wa lara re mo si mo daju pe eyin lobaloba ko ni kabamo pe e gbaruku tii.”

Gomina Abiodun wa ro awon oba pe ki won jowo ba oun se Adura fun un tinutinu bi won se see fun oun nigba ti oun n dije sipo Gomina lodun 2019 .

Bee ni Gomina tun ro awon lobaloba lati se atilẹyin fun igbakeji oludije gomina, Abileko Kudirat Abiodun Adegunwa-Balogun, o si n ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii oṣiṣẹ to ni iriri to si je akikanju to maa le se atileyin to daa fun Sẹnetọ Adeola.

Nígbà tí ó ń tẹnu mọ́ àwọn àṣeyọrí ìjọba rẹ̀ ní Ile ijebu Gómìnà Abiodun sọ pé àwọn ìlérí tí òun ṣe fún àwọn ọba nigba ti oun wa gbà adura lenu won ni oun ti mu pupo ninu re se ti oun si mo pe eni to n bo leyin oun ma a se awon eyi to ba ku ati awon nnkan mii ti won ba fe ko se fun won.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Sẹ́nétọ̀ Adeola menu ba awon Aseyori ijoba Dapo Abiodun o si seleri fun won pe oun tun ma mu idagbasoke to loorin ju bee lo ba agbegbe naa ati Ogun Waterside lasiko ijoba oun.

Be lo seleri pe oun ma je ki ise Epo fifo tunbo gberu sii ti oro Ebute fun awon oko oju Omi si maa wa si imuse, ti Ile ise afefe Gaasi olokola (Olokola Liquefied Natural Gas) maa bere ise ni pere u

Olùdíje fún ipò gómìnà ní ẹgbẹ́ òṣèlú APC náà tún ṣèlérí láti ṣètìlẹ́yìn fún bi won se ma da ìpínlẹ̀ Ijebu sile.

“Mo mọrírì ìtìlẹ́yìn tí eyin lobaloba ila oorun ipinle ogun fun ijoba Dapo Abiodun mo si n beyin, e jowo e fun emi naa ni iru atileyin bee.Tori iyen lo maa mu ko rorun fun ijoba wa lati maa mu idagbasoke ba ipinle ogun.

Oba Lawrence Jaiyeoba, Alága Ìgbìmọ̀ Ile Ijebu àti Orimolusi ti Ijebu-Igbo, fi dá Gómìnà Abiodun lójú pé àwọn ọba maa ṣètìlẹ́yìn fún Sẹ́nẹ́tọ̀ Adeola láti di gómìnà.

O wa ro Seneto Solomon Olamilekan Adeola lati mu awon ileri to se fawon se to ba di Gomina ipinle ogun

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button