Akinde ro omo naijiria lati wo awon aseyori ti adari ajo JAMBU se tele.. . ki won to sedajo lori isele to waye ninu idanwo Jambu odun 2025

Rekito ile eko gbogbonise ilaro, omowe Akinde Mukail Aremu ti ro awon omo orile ede Naijiria pe ki won sagbeyewo awon aseyori ti eka JAMBU ti se seyin ki won to dori ipinu lori isele to waye sawon akeko to kopa ninu idanwo JAMBU ti egbaa odun o-le marunlelogun yi.
Rekito ile eko gbogbonise ilaro, omowe Mukail Akinde lo soro yi fawon oniroyin nigba ti won n fi oro wa lenu wo ninu ofisi re to wa ninu ogba ile eko gbogbonise ilaro ni ojokerindinlogun osu karun odun egbaa o-le marunlelogun yi, nipa ero re lori isele to sele sawon ojuko idanwo JAMBU kan lorileede Naijiria lasiko ti awon akeko se idanwo JAMBU ti odun 2025 yi ati igbese to ye kawon omo Naijiria gbe lori oro naa.
Akinde wa ro awon omo orile ede Naijiria lati se agbeyewo awon aseyori ti oludari eka idanwo JAMBU, Ọjọgbọn Izak Oloyede tí se seyin ki won to dori ipinu ti won fe de lori oro re.
“Ile eko gbogbonise ilaro naa wa lara awon ojuko ti awon akeko ti se idanwo ko si si wahala kankan lodo wa nibi “.
Ti a ba wo awon ti won se idanwo naa a ma rii pe awon to se daadaa lo po ju awon ti ko se daadaa lo.
“Die lara ohun to fa ifidiremi awon mii ni aikawe daadaa. Tori ajo JAMBU ti se opo idanileko fawon akeko lori bi won se le fi komputa sise won lona to peye”.
Pelu awon igbese ti ajo JAMBU ti gbe yi, mo mo pe asise eka ero ati aijara mo nnkan lo fa awon nnkan to sele sawon akeko yi.
Looto inu wa ko dun si nnkan to sele a si ba awon ti nnkan selesi kedun, amo ko ye kawon eeyan ma so pe ki won yo adari ajo naa kuro nipo yen .
” nnkan ti Ọjọgbọn izak to je adari ajo JAMBU lorile ede Naijiria se to dun mo mi ninu ni bi won se kede pe kawon omo ti nnkan to seleyi kan se lo tun un se lai ni san owo kankan rara.
Igbese yi fi han pe ire awon akeko naa je oludari ajo JAMBU logun gan an.
” Mo wa n fi asiko yi ro awon akeko naa pe ki won kawe won daadaa ki ojo idanwo naa to pe”.
Aremu sapejuwe ilosiwaju to ti ba eka eto JAMBU latigba ti Ọjọgbọn Izak Oloyede ti di adari ajo JAMBU ni Naijiria gege bi eyi ti ko seleri.
” akeko nilo lati kawe tori ko si aye fun jiji iwe wo mo ninu idanwo JAMBU .
Omiran nipe ko Saye fawon obi lati ma se bo se wu won lasiko tawon omo won ba n se idanwo bi ti igbakan mo.
Be ni awon opo atunse ti ojogbon Oloyede se si eka jambu ti je ka le begbe pe lawujo eto eko lagbaye.
‘Awon igbese yi je ko dawa loju nile eko FPI nibi pe ojogbon oloyede si maa mu opo ilosiwaju ba eto eko orile ede Naijiria tawon omo naijiria ba faye gbaa.
Mukail wa ro awon obi lati ma boju to awon omo won to wa nile eko.’ E wo omo to wa nile eko to n lo foonu olowo nla tabi to gbe moto boginni wale , o ye kawon obi beere ibi to ti ri owo ra awon nnkan bee .Tori ibi tiru omo be ba ti ri owo ra nnkan be ni okan re ma wa,okon re ko ni si lara iwe ti won ni ko lo ka’.
” idi niyen to se ye ka sewadi opo awon akeko to fidiremi tabi kada awon obi won lebi pe awon naa ko boju to awon omo won daa daa. Ki i se adari ajo jambu nikan lo ye ka ma soro si”. “Tori adari ajo jambu ti mu opo ilosiwaju ba eto eko orile ede Naijiria”. Gege bo se so!
Be ni Akinde Mukail dupe pupo lowo aare Tinubu ati minisita eto eko Dokita Maruf Tunji Alausa fun bi won se fi kun awon owo ti won ya soto fun eka eto eko lorile ede Naijiria paapaa eka kan ti won n pe ni Tvet SECTOR to n ri si bi won se n ko awon akeko nise owo.
“Atileyin ti ijoba apapo fun eka yi lo je ko ran wa lowo lati se opo masinnni elese meta to n lo ina , a si tun se eyi ti won fi n se epo ati opo awon masinni mii”.
Nigba ta lo si Abuja ti won ni ka ko awon nnkan taa ti se wa ile eko gbogbonise ilaro lo gba ipo akoko.
” Mo tun ranti : nigba ti mo di rekito ni ojoketadinlogbon osu kesan odun 2022 eka ikeko merinlelogun lo wa nile eko yi amo ni bayi a ti ni eka ikeko to je mejidinlaadota lo”.
“Awon eka ikeko ta fi kun un lo dawa loju pe o ma tunbo tun ojo ola awon odo wa ati orile ede Naijiria se”.
‘Tori agbagbo pe owo to ba dile ni esu ma n wase fun amo ti owo awon odo wa ba n ha nigba-gbogbo won o ni raye huwa ti ko dara.
Rekito Akinde wa dupe lowo Seneto Olamilekan Adeola Yayi fawon nnkan to n se sile eko naa ati bo se tun fi mefa kun moto to fun ile eko naa tele, nigba to rii pe a n lo marun akoko daadaa.
” nigba kan seneto fun wa ni awon moto keekeeke marun kan pe ka ma fi gbe awon akeko kiri inu ogba ile eko wa amo ni bayi won ti tun fun wa ni mefa mii sii: Gbogbo moto taa ni ti di mokanla bayi .
“Ni bayi a ti n Seto bawon moto wa se fe ma lo ko awon akeko to wa ni ona Oja-Odan ati aarin igboro ilaro ki nnkan tunbo le rorun fawon akeko wa.




