Akeko ku leyin to mu Omi ninu ogba Ile Eko, Ijoba ati Ile Ise olopa ko gbe igbese to ye labe Ofin.

Kayefi nla lo je pe ijoba ipinle Ogun, labe idari Gomina omoba Dapo Abiodun ati Komisana Abiodun Alamutu to je Oga agbofinro ni ipinle Ogun ko mu abajade iku to pa akeko Omo odun meedogun to mu Omi ninu Ile Eko alakobere Presentation ti ijo katoliiki to wa ni oke okuta nilu Ilaro jade titi di bi a se n ko Iroyin yi jo.
I beere to n ja kudu lokan awon eeyan ni pe se Ile ijosin naa lo ni ki ljoba ipinle Ogun ati Ile Ise olopa ma gbe igbese to ye lori Oro naa ni, Abi toripe awon ti Oro yi selesi ko Fi be e lenu loro lawujo ni won ko se gbe igbese to ye ni.
Fun opo eeyan ti ko ba mo bi isele naa se sele ati idi ti o se ye ki ijoba ipinle Ogun pelu Ile Ise olopa gbe igbese to ye lori Oro naa; alaye ni kikun Lori bi Oro naa se sele ree.
Iroyin iku Falolu Ope Oluwaseun ti Omo odun meedogun lo gba Igboro lojo kerindinlogun osu kesan odun 2024.
Awon to Fi Iroyin yi to Iroyin Yewa leti je ko di mimo pe omodekunrin yi ati awon akegbe re ni won jo lo gba boolu ninu ogba Ile eko alakobere Presentation ti ijo katoliiki to wa ni oke okuta nilu Ilaro.
Won ni igba ti oungbe n gbe Omo naa ni o lo si ibi ero Omi to wa ninu ogba Ile Iwe naa, won ni o si omi na, amo omi ko yo ni Isale, lo ba lo si ni idi fita loke ti omi si yo si i lenu nibe.
Nigba ti o Fi ma di irole ojo Sunday ojo keedogun ti isele naa sele lo ba bere si ni kigbe Inu rirun. Won ni ki lo je nibi ti o lo o ni omi lasan ni Oun mu nigba ti Oun lo gba boolu ninu ogba Ile eko alakobete naa . Nigba ti won Fi ma gbe e de osibitu adani kan won ni awon ko le se itoju re pe ki won ma gbe lo si Ile iwosan ijoba. Eyi lo mu ki won gbe lo si Ile iwosan ijoba ipinle Ogun to wa nilu Ilaro nigba ti o Fi ma gba afefe gaasi keta tan dokita ni ki won ma gbe lo si osibitu ijoba Apapa to wa ni Ilu Abeokuta.
Ohun ti dokita ko sinu Iwe ni pe oti mu majele ninu Omi to mu ti eyi si ti se akoba fun Ilera re.
Won ko tii gbe Omo na kuro nibe ti emi re Fi bo.
Awon ti won mule ti Ile eko na Fi esun kan Oga Ile Iwe na pe Oun lo Fi kemika ti won Fi n pa kokoro sinu Omi na Tori o ti ma n leri pe Oun ma Fi kemika si Omi naa Tori awon eeyan to ma wa n ji Omi na pon.
Leyin ti Omo na ku awon kan kora won Jo lati lo Fi ehonu won han amo Baba Omo naa so pe ki won ma se bee tori Oun ko ni Owo lowo lati Fi ba Soosi na se ejo.
Nigba ti a lo Fi Oro wa Eni to je olori Ile esin naa ni Ilaro lenu wo o je ko di mimo pe looto kemika ti Omo na mu ninu Omi na lo pa a .Sugbon aigbonran re lo fa isele to sele sii, ka lo gboran ni ko ni lo gba boolu nibe, be ni ko ni lo mu Omi nibe.
Lesekese ti awon oludasile Ile eko na gbo Ohun to sele ni won ti Fi to olopa leti pe ki won lo ba awon daabobo Ile eko na ati oluko ti awon eeyan Fi esun kan.
Be ni Won pe awon obi ti won mu Omo wa sile Iwe na won so fun won pe looto kemika to wa ninu Omi ti Omo na mu lo paa amo kiise kemika ti o n pa nnkan ni won Fi sibe kemika ti won
Fi n se Itójú omi ni won Fi si Inu omi naa.
Amo awon to wa lagbegbe na ni iro ni won n pa pe kemika to le pa nnkan ni won Fi sibe,Tori nigba ti won si tanki omi naa se ni kemika run jade ninu re.
A mo mama Omo ni Oun ko lowo lowo amo Oun ni lgbagbo pe Olorun ati awon ijoba ma se Idajo ododo.
Idi niyi ti awon Omo niajiria se Fe ki ajo to n ri si Eto eko nipinle Ogun ati komisana fun Eto ilera Dokita Tomi Coka ati ajo eleto ilera pelu awon olopa dide lori Oro naa ki won se iwadi finifini ki won si so fun Omo naijiria iru kemika ti won Fi sinu Omi naa ki Idajo ododo le waye.
Ni bayi ti e ti Mo bi isele naa se waye ki ni ero yin .
E ma gba gbe pe ijoba wa fun didaabobo emi ati dukia araalu be ni awon agbofinro n sise po pelu ijoba ki ofin le fidi mule daadaa.
Se o wa ye ki ijoba so bi Oro naa se je fun araalu ki won le ri Eko ko nine Abi ko ye?.
