Ìdílé Obasanjo pín si meji nítori oselu awon meji tele Yayi nigba ti Iyabo ati awon toku tele Ladi Adebutu

Nnkan ti koseleri ni ipinle ogun lo n sele lasiko ti Seneto Solomon Olamilekan Adeola YaYi setan lati du ipo Gomina labe Asia ẹgbẹ Oselu APC lodun 2027.
Leyin ti Iyabo Obasanjo Bello ati awon mii jade fun ipo Gomina labe Asia ẹgbẹ Oselu APC ninu eto idibo Abele ẹgbẹ Oselu naa amo to je pe Seneto Solomon Olamilekan Adeola YaYi ni ẹgbẹ fa kale ti won si ni kawon to ku lo gbaruku tii ni opo awon oloselu ti ko te lorun ti bere si ni gbe awon igbese mii.
Bi awon kan se n gba Ile ejo lo lawon mii n lo sinu ẹgbẹ Oselu mii.
Leyin ojo melo kan ti Abileko Iyabo Obasanjo Bello kuro ninu ẹgbẹ Oselu APC lo ba pada sinu ẹgbẹ Oselu PDP to wa tele, to si lo dije fun ipo Seneto aarin gbungbun ipinle ogun.
Kete leyin ti Iyabo Obasanjo Bello lo sinu ẹgbẹ Oselu PDP ni awon omokunrin Obasanjo meji, Dókítà Olugbenga Obasanjo àti Ọ̀gbẹ́ni Olujuwon Obasanjo lo ba Seneto Solomon Olamilekan Adeola ti won si fi daa loju pe digbi lawon wa leyin re.
Nigba ti Seneto Solomon Adeola n tewogba awon meji naa o ni “inu mi dun láti gba àwọn ọmọ baba wa àti Ààrẹ tẹ́lẹ̀, Olóye Olusegun Obasanjo, GCFR, ní ilé mi ní ilu Abeokuta, Dókítà Olugbenga Obasanjo àti Ọ̀gbẹ́ni Olujuwon Obasanjo wá bẹ̀ mí wò won gboriyin fun mi nipa awon iṣẹ́ rere ti mo ti se nínú oselu won si ṣèlérí fun mi pe awon ma se itìlẹ́yìn fun mi ki n le jawe olubori gẹ́gẹ́ bí olùdíje gómìnà APC fún Ogun ní ọdún 2027,” gege bo se so.
Be ni Seneto Iyabo Obasanjo Bello, ẹni tí ó ti ṣojú fún aarin gbungbun ipinle Ogun láàrín ọdún 2003 sí 2007, ri to tun sese pada sinu ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tì je ko di mimo pe oun tun maa jade fun ipo Seneto aarin gbungbun ipinle ogun lodun 2027.
Ẹgbẹ Oselu PDP ni bi Seneto Iyabo Obasanjo Bello se pada sinu ẹgbẹ PDP to si tun setan lati dupo Ile igbimo Aṣòfin apapo labuja ma je ko rorun fawon lati le ẹgbẹ Oselu APC kuro nipo ijoba ipinle ogun lodun 2027.




