ÀṢÀ ATI ÌṢE

Omi Odo OleOmi Odo Oleyo ma mu eto oro Aje ru gogo sii ti ijoba ba le satunse re bi Ori oke Olumo ati osun -osogbo- Ọba Amusa Dosunmu

Elebute ti ilu  Ebute-Igbooro, Oba Amusa Adetunji Dosunmu, ti ke si ijoba ipinle ogun  lati se wa tun Odo Oleyo se ko ri bii Ori ole olumo ni ipinle ogun ati Odo Osun-Osogbo ti awon eeyan ma n lo won ni ipinle osun.

Kabiesi soro yi lojokerindinlogun osu kesan odun egbaa odun o-le merindinlogbon yi nigba ti won n lo bo Odo náà lasiko ti won bere ajodun Odo oleyo.

Bo tilejepe Odo naa to wa tipe ti awon Babanla won ti ma n bo o ki Opo to papoda.Amo eyi je akoko iru re ti gbogbo ilu panupo lati tun bere si ni ma bo Odo náà pada.

Oba Dosunmu sọ pé Oleyo Waterfall wà ní ilẹ̀ Ebute-Igbooro, ti awon Baba nla awon si ma n bo ti won ba ni awon isoro .

“kabiesi tenu moo pe Ebute-Igbooro ni o ni Omi-odo Oleyo,”

Ọba Amusa wa ro ijoba ìpínlẹ̀ Ogun láti wa tun Odo naa se ko le di ibi tawon eeyan ati ma wa gbafe Tori Odo oleyo nikan si ni ibi ti Omi ti n san jade lati inu apata ni ipinle ogun.

“A fẹ́ kí ìjọba ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti gbé e ga, kí ohun gbogbo lè lọ láìsí ìṣòro. A Fe kí wọ́n ràn wá lọ́wọ́; ìyẹn ni ohun tí a fẹ́ kí ìjọba ṣe fún wa,” gege bo se so.

Bákan náà, Balogun ti Ebute-Igbooro, Olóye Jeremiah Ijiola, ṣàpèjúwe Oleyo gẹ́gẹ́ bí ohun ìní àdánidá àti àṣà tó yanilẹ́nu tí a kò tí ì ṣe àwárí rẹ̀ ri ni ipinle ogun.

Ijiola sọ pe awọn ọmọ  agbegbe naa ti maa n lọ si ibi isun omi lati gbadura, o si fi kun pe tipe tipe ni awon Babanla awon ti ma n wa gbadura ninu Odo naa.

Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, I ijoba ba mu ìdàgbàsókè tó tọ́ ba Odo naa o maa tunbo mu ilosiwaju ba eto oro aje agbegbe naa ati ipinle ogun lapapo.

“A fẹ́ kí ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun ràn wá lọ́wọ́ láti sọ ọ́ di ohun ńlá. Nítorí pé pẹ̀lú orísun omi bí èyí, ìjọba lè rí owó pa wọlé láti inú rẹ̀,” Ijiola sọ.

Ó rọ ìjọba láti pèsè àwọn ètò ìdàgbàsókè tí yóò jẹ́ kí àwọn arìnrìn-àjò lè dé ọ̀do Oleyo, ó sì fi wé Olumo Rock ní Abeokuta, èyí tí wọ́n ti ṣe àgbékalẹ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ibi ìgbafe àwọn arìnrìn-àjò.

Ijiola sọ pe awọn aṣoju ijọba ti ṣabẹwo si Odo naa leyin ti ilu bere si ni satunse  re ti won si Fi da awon loju pe ijoba ma wa tun Odo naa se .

Abore ilu  Ebute-Igbooro, loye Alani Olusola, sọ pé ilu ma se gbogbo nnkan to ba ye lati mu ilosiwaju ba Odo naa.

Ó rọ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ àti àwọn olùgbé ilu naa láti má ṣe isese sile. (Isese) ṣe pàtàkì. A kò gbọdọ̀ ju àṣà wa sílẹ̀.”

Olórí Ọ̀dọ́ ilu  Ebute-Igbooro, Olóye Emmanuel Akan, sọ pé Odo Oleyo kì í ṣe nnkan to sese hu jade , o ti wa tipe ti awon Baba nla awon ti ma n boo .

Ó ro  ìjọba láti wa tun ona to wo Odo naa se ko le rorun fawon eeyan lati ma wa gbafe nibe.

Olóye Akan dupe lowo Alaaji Ibrahim Dende Egungbohun, Onorebu Wahab Aruna ati Akeweje ilu Ebute-Igbooro Olóye Obasanjo ojugbele pelu awon Omo ilu to ku fun atileyin won lati riipe Odo naa di ibi ti awon eeyan ti wa n gbafe.

Bákan náà, Akeweje ti Ebute-Igbooro, Olóye  Obasanjo Ojugbele, rọ ìjọba ìpínlẹ̀ ogun  láti wa se atunse Odo naa, ó ní iyen ma je ki ero oro aje agbegbe naa,ipinle ogun ati orileede Naijiria tunbo ru gogo sii Tori Opo awon eeyan lo ma a Fe lati ma wa wo Odo naa lati orileede mii.

“Ṣíṣe èyí yóò mú kí ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ Ogun pọ̀ sí i,” Ojugbele sọ.

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button