Omooba Segun Adewala gbosuba fawon Oba Iwo-oorun ipinle ogun bi won se da Owo Ladi Adebutu pada
Omooba Segun Adewala ti a tun mo si OSA to da ẹgbẹ (OSA For YaYi) sile lati ma Fi polongo Ibo Alajobi fun Seneto Olamilekan Adeola ti gbosuba kare lai fun awon lobaloba nile Yewa-Awori bi won se ko Owo ti oludije sipo Gomina labe ẹgbẹ Oselu PDP, Onorebu Oladipupo Adebutu gbe wa fun won lasiko to wa fi eroungba re han pe oun gan ma jade fun ipo Gomina ipinle ogun lodun 2027.
Omooba Segun Adewala ṣàpèjúwe ìgbésẹ̀ àwọn ọba gege bi apeere rere fawon Omo ati olugbe Iwo-oorun ipinle ogun. Bi awon lobaloba se da Owo naa pada ti fi han pe enuwon ti ko lati di ibo Alajobi fun Seneto Olamilekan Adeola YaYi.
Be lo tun Fi han pe isokan ati àlaafia ti wa laarin awon lobaloba wa, won si ti dori ipinnu lati pa egun madi Gomina to n bawaja tipetipe je.
“O damiloju pe ti gbogbo awon lobaloba to wa ni Iwo-oorun Ipinle ogun bale duro lori ipinnu won pe awon ko ni gbà Owo lowo oloselu mii afi eyi to jade lati Ile Yewa lati inu ẹgbẹ Oselu APC, idaniloju ti wa pe nnkan ti a n wa ma tewa lowo lodun 2027″.
” Mo wa n ro gbogbo awa ti a je Omo ati olugbe ipinle ogun lati se bi awon lobaloba wa ti se, e jowo e ma je kawa naa gbà Owo lowo oloselu mii “. Ibo Alajobi ni ke je ka di fun Seneto Olamilekan Adeola YaYi.
Ti gbogbo wa ba le se ipinnu bi awon lobaloba wa ti se odaju pe Yewa-Awori lo ma di Gomina lodun 2027.




