ÒṢÈLÚ

Die lara awon eto idagbasoke to kan Ile Yewa-Awori laarin odun meta isakoso Aare Bola Tinubu

Bi le se n mo tile n su ni ojo naa ti Aare Tinubu de ipo Aare orile ede Naijiria n lekan sii.

Aipe yi ni won se ayeye odun keta ti won de ori ipo Aare orile ede Naijiria to won si soro nipa awon nnkan to won ti se laarin odun meta ATI awon nnkan mii ti won si maa se.

Looto Ara isoro to wa Nile to Aare Bola Tinubu jogun re lowo Aare Muhammad Bihari lodun 2023 ni oro eto aabo to n mehen , iyen idamu awon ajinigbe ati agbeni pa to n koju ise takun takun ti awon eso alabo orile ede Naijiria n se po gidigidi to fi je ki opolopo awon ara ilu ma pariwo ki Aare Bola Ahmed Tinubu gbe igbese ju bi o se n gbe e yi lo, sibe opolopo igbese ati ise daa daa ni Aare ti se lati Odun Meta ti o ti wa lori ipo naa jakejado orileede Naijiria.

Die lara awon ise idagbasoke ti Aare Bola Tinubu se ni apa Iwo-oorun ipinle ogun ni, Titi marose Badagiri si Sokoto, to bere lati ilu Eko to gbà Iwo-oorun ipinle ogun,koja lo si oke Oya.

*Sise Opopona Marosa Badagry si Sokoto*

Lakoko, Ise to lami laaka ti ijoba apopo n se lorileede Naijiria to si de ipinle Ogun ti o fi kan Yewa-Awori gbon gbon ni opopona Badagry ni ilu eko to fi de Sokoto ni oke oya lohun.

Pupo ninu ibuso ona yi lo gba agbegbe ile Yewa-Awori koja ti ise takun takun si n lo lowo bayi.

Nigbati opopona Badagry si Sokoto yi ba fi maa pari, opolopo aanfani lo maa si sile leka eto oro Aje, Irin ajo to ja geere fun awon arinrinajo, idagbasoke Eto Ile gbigbe ni gbogbo agbegbe yi.

*Ikeji: Ile Eko Fasiti Imo Ero Ilu Ilaro*

Ikan lara awon aanfani mii ti Iwo-oorun ipinle ogun tun gbadun laarin odun meta ijoba Aare Bola Tinubu ni ti igbega ti won mu ba Ile Eko gbogbonise ilu ilaro, bi won se so o di ifasiti imo ero ilu ilaro., ( Federal Polytechnic Ilaro) ti won so di IFasiti imo Ero Ilu Ilaro, iyen (Federal University of Technology Ilaro) .

Opolopo awon omo ati olugbe Ile Yewa lo ti n gborinyin ti won si n dupe lowo Aare Bola Tinubu lori bibuwo si iwe ofin to yi Ile Eko gbogbonise naa pada si ifasiti imo ero.

Bi opopona ti won n balo se mu igbega ba agbegbe yi ni Ile eko yi naa maa mu igbega ba Ile Yewa-Awori leka eto oro aje, eto eko, idagbasoke ilu ati be be lo.

Iketa:*Atunse Opopona Marose Ota si Idiroko*

Ba kan na ni atunse titi marose OTA si Idiroko ti ijoba apapo tun n se pelu afara meta ti ona na yi o ni ni, Oju oore OTA, Ile ijosin winners ati lori Odo Iju OTA ni awon ara ilu ati olugbe Ile Yewa-Awori ti n gborinyin fun ijoba apopo labe idari Aare Bola Tinubu pe odara lopolopo ti eyi si tun maa mu eto oro aje laarin orileede Naijiria ati orileede Benin gberu sii.

Ikerin:*Ile Eko Awon Olopaa Naijiria ni Erinja*

Aare Bola Tinubu tun buwo lu Ile Eko tuntun fun kiko awon Olopaa orile ede yi ni ilu Erinja ni ijoba ibile Gusu Yewa. Idasile yi niise pelu bi Ile Eko fun awon Olopaa ti o wa n’i ilu Kano yi o se nipa sii nipase ipase eka ilewe ikeko fun awon akeko kakiri orile ede yi.

Aare Bola Tinubu wa fowosi nina bilionu meedogun fun kiko Ile Eko ati awon Ile ati Ohun ti yi o mu nkan derun ni Ile Eko fun awon olopaa yi.

Idaniloju wa pe Aare si ma se pupo sii ti won ba fi maa lo odun mejo nipo Aare orileede Naijiria.

Idi niyi to Fi ye ki awon eeyan Iwo-oorun ipinle ogun se gbodo gbaruku ti Aare Bola Tinubu ninu eto idibo to n bo ki won si fi ibo won gbe Aare wole leekeji ka le gbadun Opo nnkan amayederu mii ti Aare Bola tun fe se fun wa ni Iwo-oorun Ipinle ogun ati orileede Naijiria lapapo

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button