Lobaloba

Ayẹyẹ ọdun kọkalelogun ti Olu Itori gori itẹ ti bẹrẹ

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni wọn bẹrẹ ayẹyẹ ọdun kọkanlelogun ti Olu-Itori, Ọba Fatai Akorede Akamọ, gori itẹ gẹgẹ bi ọba alaye ilu naa,

 

Ipade oniroyin ni wọn fi bẹrẹ nibi ti Ọba ọhun ti bawọn oniroyin sọrọ lori awọn eto ti wọn ti la silẹ fun ayẹyẹ naa ti yoo pari lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

 

Awọn eto loriṣiiriṣii lawọn ti la kalẹ fayẹyẹ ọhun,lara ẹ

ni eto ẹkọ ọfẹ, sisanwo awọn tara wọn ko da ni ọsibitu, riro awọn ọdọ lagbara atawọn nnkan mii-in.

 

Ọba Akamọ sọ pe awọn ọmọleewe poli ICT, Itori, ti wọn jẹ ogun ni wọn yoo jẹ anfaani eto ẹkọ ofẹ, ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un kan Naira, ẹnikọọkan, bẹẹ lo ni oun yoo sanwo ọṣibitu fawọn tara wọn ko ya ti wọn da duro ni ọsibitu jẹnẹra to wa ni Ijaye ati Sacread Heart, to wa niluu Abẹokuta.

 

O fikun ọrọ ẹ pe awọn yoo tun nawọ sawọn to wa ni ọgba atunṣe Ibara, ti wọn ko ri owo beeli wọn san. Bakan naa lo ni ile awọn ọmọ ti ko niya iyẹn Stella Obasanjo Orphanage home’’ naa ko ni gbẹyin lara awọn ibi ti wọn yoo ṣabẹwo de.

 

Nigba to n sọ nipa ipenija toun naa ti koju ri, Ọba Akamọ sọ pe, ‘’Igba kan wa ti ara iya mi ko ya, to wa ni ọsibitu UCH, niluu Ibadan, ti mi o rowo san, ounjẹ ajẹku awọn alaisan la n jẹ, ohun lo mu mi pinnu lọkan ara mi lati sawọnwo awọn to ku diẹ kaato to wa ni ọsibitu’

 

 

Bẹẹ lo mẹnuba ẹsun ti wọn fi kan-an lori ọrọ ilẹ, Akamọ sọ pe, ‘’ Mi o bawọn ta pilọọti ilẹ to kere, depodepo pe maa ta nla niluu Itori latigba ti mo ti jọba.Ijọba lo ni awọn ilẹ ti aawọ wa lori ẹ yii koda aafin ti mo wa yii, ilẹ ijọba ni, mo pe ẹni to ba sọ pe oun loun nilẹ ki wọn jade pẹlu ojulowo iwe ilẹ C of O.

 

 

” Mo ti fawọn eeyan ni ilẹ ọgbọn eeka lọfẹẹ daadaa.Gbogbo nnkan to n ṣẹlẹ si wa oore-ọfẹ, eeyan ki I ba Ọlọrun jijakadi. A ni lati ṣe fawọn eeyan pada’’.

 

Ọba Akamọ wa fi akoko naa gba awọn ọdọ lamọran lati jẹ aṣoju rere, nitori idi eyi lawọn ṣe nnkan ti yoo mu wọn niṣẹ niluu, nipaṣẹ ironilagbara ti wọn fẹẹ ṣe fun wọn.

 

O waa gboriyin fun Gomina Dapọ Abiọdun lori igbiyanju ẹ fun idagbasoke imayedẹrun to ṣe siluu Itori. O ni o ti fi apẹẹrẹ lelẹ lati sọ ẹgan dofo lori ọna Itori- Ewekoro si marosẹ Eko.

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button