ÌSÌN

Sunday  ljidele sin Oku mama re Elisabeti Gbemisola ijidele tilu tifon.

Onimoero Sunday  ljidele to fi ilu Eko se ibugbe lo ti se ayeye ikeyin fun mama re oloogbe Elisabeti Gbemisola ijidele ti o sun ninu oluwa ni osu kejila odun 2024 .

Eto isinku naa lo waye lojo kokonla osu kini odun egbaa odun o-le marunlelogun  ni ilu Adja Quere ni ijoba ibile Ipobe, ni orile ede Olominira Benni.

Nigba ti eto isinku naa n lo lowo ninu ijo Catholic to wa ni ilu Adja Quere ni Alufa ijo to se iwasu eto isinku naa ti sapejuwe abileko Elisabeti Gbemisola ljidele ti opo ma n pe ni (Nee Adechi)  gege bi mama ijo Catholic ti ilu Adja Quere. O wa ro awon omo oloogbe lati ma tele apeere mama won ki won si maa sin olorun deedee.
O ni ” Mo fe ki e mo pe onigbagbo ni mama won ko si kuro ni ilana olorun titi won fi ku ,igba ti mama di mama ijo ni won tun ile ijosin yi se bayi.” Mo ro yin lati ma nawo si ile olorun bi i ti mama .
” Mo fe ki e ni idaniloju pe awon iwa rere ti mama hu ma je ki won wo ijoba orun.
Sunday ijidele ni ” oluberu olorun ni mama, won si ma n lo sile ijosin deedee, won si fi ko awa naa lati ma lo sile ijosin deedee, ka si ma fi nnkan ti a n ko silo”.

Abileko Juliana Ijidele naa ni ” looto mama wa ti pe omo odun mejilelogorun  102y amo mi o le paro fun yin iku mama dun mi gan . Mama je enikan to niwa tutu ti won si ma n je ko dawa loju pe fifi ti olorun si ipo akoko lo dara ju ninu igbe si aye eda . Won kii fi ile ljosin sere rara, won si ma n ko eeyan mora, aaro won ma se gbogbo awa omo won gan- an.
Be e  ni gbogbo awon omo omo oku lati ori Pelumi ijidele ati awon to ku sapejuwe mama bii Eni to niwa tutu to si ma n ko omode more, gbogbo awa omo omo won ni mama ma n ra nnkan fun bi won se dagba to yen titi won fi ku.

Balogun ilu Ebute- lgbooro oloye  ijiola ati Baale orile igbooro oloye Abidemi Akorede naa sapejuwe mama ijidele bi Eni to nife awon eeyan to si mu ilosiwaju ba ilu Ebute lgbooro nigba to wa nibe ko to dipe won lo si odo awon omo won nilu eko .
Balogun tun dupe lowo olorun fun bi o se fun mama ni awon omo to ni iberu olorun bii tie.
” tori iwa to dara bii ti mama ti Sunday ljidele ni lo je ki awa oloye ilu Ebute-Igbooro wa nibi loni .
Oloye Baale Abidemi Akorede naa sapejuwe oloogbe Elisabeth gege bi Eni to ni iwa to daa.
“Baale orile igbooro oloye Abidemi Akorede ni “atigba ti mo ti wa ni kekere ni mo ti mo mama won si feran awa omo keekeeke gan an .
” Mo wa n ro awon ti won wa nibi loni paapaa awon obinrin lati ma nife awon omo keekeeke ki won ma je Eni to n kanra mo awon omo keekee ke ati awon agbalagba tori iyen lo ma n je ki won ma pe elomii loruko ti kiise tire .
Be ni Abileko Debora ojugbele ati Abileko Ramot Apena ti opo mo si mama leke naa sapejuwe mama bi Eni to fi apeere rere lele fawon obimrin lati ma tele.
Lara awon lobaloba ti won wa nibi oku naa ni  oba Oyebanji Olowobese oloja ti ilu oja odan ati awon lobaloba ati Baale lorile ede Naijiria ati orile ede olominira Benni wa nibi ayeye oku naa .

Awon eeyan Jankan jankan ti won tun wa nibi ayeye oku naa ni, onisowo ni ,Alhaji Ibrahim Dende Egungbohun ati awon egbe inu midun scord patapata pelu awon asoju oloselu ile olominira Benni ni,Olaegbe ati awon osise Sevron ni ipinle Eko pelu awon egbe Elepo ati awon sewosewo  nile olominira Benni.
Comureedi Isa owolabi Olude ati ogbeni Sunday Adesi to je manija ile ifowopamo Ocon success ti ilu oja odan naa wa nibi ayeye oku naa.

Bi Segun Oluwole ti opo mo si Alawada se n pawon eeyan lerin ni olorin juju naa tun n fi ilu ati orin  siwon nibadi.

Paripari re Onimoero Sunday ijidele wa dupe lowo gbogbo awon to wa sibi eto isinku naa lati ori Oloja tilu oja odan lorile ede Naijiria, Oba Onimoero Oyebanji Olowobese  ati gbogbo awon eeyan jankan jankan to wa sibi oku naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button