Ile eko gbogbonise ilaro gba akeko egberun mokanla ati oodunrun-le-merin-din-logun wole si ipele ND,HND ati ND Odfel pelu HND odfel ti saa ikeko 2024/2025

Oni ojo kerinla osu keta odun egbaa odun ole marunlelogun yi ni ile eko gbogbonise to wa nilu ilaro pari eto igbaniwole fawon akeko ti won fe wole sile eko naa fun ti saa ikeko 2024/2025.
Ayeye Igbaniwole naa lo waye ninu gbogan ipade Rahim Oloyo to wa ninu ogba ile eko naa,ti won si se atagba re lori ayelujara fawon akeko to wa lawon gbogan mii to wa ninu ogba ile eko naa.
Rekito ile eko naa,Dokita Mukhail Akinde dupe lowo awon obi ati akeko naa fun bi won se yan ile eko gbogbonise ilaro lati wa kawe.
Be lo ba awon akeko naa yo fun bi won se wa lara awon akeko to se e mu yangan ti won mu ninu awon akeko egberunmeje o le ti won fe wole sile eko naa.
Ninu awon egberunmeje ogorunkan ati mokanlelogota 7,161 to fe wole si ipele ND, to si je pe egberunmerin ati eedegbeta o le merindinlaadorin 4,566 pere ni won mu ninu won.
Be ni awon akeko Part time ti ND je 4,592, egberunmerin ati eedegbeta ole mejilelaadorun to si je pe awon egberunmeji egberin ole metadinlaadorun 2,887 ni won mu .
Awon ti won fe wole si ipele HND je egberunmerin ole metaleleedegberin 4,703 ti won si mu awon egberunmeta eedegberin ole marunlelaadorin 3,775 ninu won.
Bi Rekito se n ba awon akeko ti won mu naa dupe lo tun n ro won lati ma ka iwe won ki won si ma tele ase ati ilana ile eko naa.
Dokita Mukhail Akinde wa ro asoju ajo Ndlea lati wa da kiloobu NDLEA sinu ogba ile eko naa.
Ogbeni Lawal to wa soju eni to je oga ajo NDLEA nilu ilaro ro awon akeko naa lati yera fun oogun oloro, tori lilo oogun oloro ma a n je ki opolo ma sise daadaa.
O ro won lati yera fawon oogun oloro kan ti won ma n pe ni Melta ati vitamin
Won kii ri i loju tabi lori bii Colorado tori laabu ni won ti ma n poo po, iyen ni kii je ki won tete ma han lara tabi loju awon to n mu un.
Paripari e o ma n tete gbemi eeyan.
“Oogun oloro mii ni Pentatosin won ma n lo o bi abere ni, o si ma n sakoba fun ara” .
O wa ro won lati ma a sayewo awon nnkan ti won ma n mu nibi ariya tori skuchi ko yato si Sobo o si le sakoba fun ara won .
Otunba Idowu Onifade to je igbakeji Onimoero ilu ilaro to wa soju Oba Kehinde Gbadewole Olugbenle Asade Agunloye kerin ro awon akeko to sese wole naa lati mu awon koko marun kan lo akoko:
ki won ma fi owo fun ara won, ki won je awofisapere rere nibikibi ti won ba wa, ki won yera fun ibinu ki won si foju si nnkan ti won wa se, ki won ma se ayojuran si nnkan ti ko kan won .Fun apeere ti won ba n se ayeye odun ibile .
O ro won lati ma se awon nnkan to ba ye ki won se bii fifowosowo pelu awon ti won gbale lowo won ati awon oluko won.
Paripari re, o ro won ki won ma a lowo ninu nnkan to ma mu ilosiwaju ba ilu ilaro ati agbegbe re.
Won ro awon akeko naa lati mo iru eni ti won je ati bi agbara won se gbe e to lati kawe ati lati se opo nnkan mii ki won le saseyori ninu eko won.
Be lo ro won lati sise lori awon ibi ti won ku die si, bii; eni to feran ko ma sere kiri nigba to wa nile tele ati eni to ma n pe ko to sun,o si ro won lati ma sun mo awon ti won mowe juwon lo.
olugba awon akeko nimoran nuju ogba FPI ro awon akeko naa lati tele oro ti asoju NDLEA so fun won ki won si yera fun oogun oloro.
Niti lilo si awon ibi igbafe bii, ile ijo ati awon ibi ayeye mii, tori eyi ko ni je ki won pa okan won po sori eko won.
O tesiwaju pe nnkan to ma ro won lowo ni nini afojusun to dara ninu eko won.
Dokita Tunde Ogunsina je kawon akeko tuntun naa mo pe ofe lawon ma n toju gbogbo awon akeko ile eko gbogbonise ilaro.
Sugbon won gbodo wa gba kaadi idanimo to ma fi won han gege bi akeko ile eko naa ki won to lanfaani sawon oogun naa.
Be lo ro won pe ki won yera fun mimu kaadi idanimo akeko mii wa sile iwosan ti won ba fe wa gba oogun.
O wa ro won lati ko Genotipe won to je ojulowo sile, ki won ma paro rara.
O kilo fun won lati yera fun oogun oloro tori awon ni ibi tawon ti ma n ye akeko kookan wo, tawon si ma mo boya o n lo oogun oloro tabi ko lo .
Niti eni to ba n saisan lasiko idanwo o je ki won mo pe anfaani wa fun iru akeko bee lati pari idanwo re leyin ti ara re ba ya ki esi idanwo to jajade.
Abileko Fatunbi je kawon akeko tuntun naa mo awon nnkan to ye ki won se ki won to di ojulowo akeko ile eko gbogbonise ilaro.
Akoko, iforukosile lori ero ayelujara hhttp /www.poly ilaro ati biometrics register ati iforukosile ninu ogba ile eko.
O je ko di mimo pe ni kete ti won ba ti forukosile tan lori ayelujara ni won ti ma sanwo ile eko won, ti won si ma gba nomba
Biometric won, leyin iyen ni won ma wa se iforukosile ni ofisi to wa ninu ogba ile eko naa.
Paripari re igbese ikeyin ti akeko naa maa gbe ni ko ko awon iwe to fi han pe o ti se gbogbo awon iforukosile naa wa sile eko naa
O ni” tori pe gbogbo yin ti gbe awon igbese yi lo je ke wa lara awon ti won gba wole sile eko gbogbonise ilaro loni.gege bo se so.


