Nitori ki Gomina ipinle Ogun le wa sibi asekagba Oronna,won yi ayeye ajodun asekagba oronna si ojo isinmi.

Ninu iroyin kan ti oloye Lekan Asuni to je alaga ayeye ajodun oronna fi sita fawon oniroyin loni ojo kerindinlogbon osu kokonla odun 2024 yi lo ti salaye pe asekagba ayeye ajodun oronna naa to ye ko pari ni ojo Abameta to je ogbon ojo osu kokonla yi ni ko ni le waye mo, ti awon si ti sun-un si ojo kini osu kejila odun 2024.
Otunba Asuni salaye siwaju sii pe, looto ogbon ojo osu kokonla ni o ye ki asepari ayeye naa waye amo nigba ti awon rii pe Gomina lpinle Ogun, Omooba Dapo Abiodun to je olori olugbalejo nibi ayeye naa maa wa nibi ayeye Ayajo lperu lojo naa ni awon se fe ki gomina farabale se ayeye naa ko si wa se ojuse re gege bi olori olugbalejo ati alejo pataki nibi asepari ayeye ajodun oronna ti odun 20204 .
Be ni oloye lekan asuni ni yato si ayeye ojo asekagba nikan ti awon sun si ojo kini osu kejila odun 2024, gbogbo awon eto to wa nile tele ni ko yipada.
Awon eto bii : Ere sisa ati eto ilera lojo isegun.
Ojoru: kabiesi ma gbalejo awon odo, olori si ma se ayeye pelu awon omo keekeeke,Egungun ati gelede naa maa waye.
Ojobo ni ayeye onigba aje ati asale poosu ma waye.
Ojo eti ni isin idupe ma waye ni Mosalasi, Asale Omooba ati aya oba, ati yiyan Sisi ilaro ma waye.
Ayeye boolu ma waye ni ojo Abameta .
Isin idupe ma waye kaakiri awon ile ijosin to wa nilu ilaro lowuro ojo isinmi ki ayeye asekagba to Bere ninu ogba Asade Agunloye Pavilion to wa nilu ilaro.
” A dupe lowo yin fun lfowosowopo yin pelu wa, a si n fojusona lati ri gbogbo eyin ti a fiwe pe ati eyin omo ilu lojo kini osu kejila ti a maa se ayeyeye asepari odun oronna ti odun 2024 yi o”


