Ayeye oniberin ti Baale Keesan orile oloye Abodunrin Adeyemi seto re ti fe bere

Baale Keesan orile ni Ariwa Abeokuta, Oloye Waheed Abiodun Abodunrin Adeyemi ti salaye pe gbogbo eto lo ti pari fun ti ayeye oniberin ti oun fe se .
Ojo kokonlelogun osu kejila odun egbaa odun-ole-merinlelogun yi ni ayeye ifomofoko maa waye nilu Eko, leyin naa ni Baale ma se ayeye ajodun ojo ibi odun ketalelogota re loke eepe. Baale tun ma se ayeye iranti iku mama re, Abileko Sikirat Abike Abodunrin ni ojo kejidinlogbon osu kejila nilu Abeokuta tiise olu ilu Ipinle Ogun.
Baale Adeyemi to fi ilu Amerika se ibugbe ,to si yan ise Amunidara laayo ni, ayeye oniberin yi je ohun manigbagbe ninu Itan Igbesi aye oun.
“Olorun ti fi oju rere han simi nilu yi ati loke okun ti mo n gbe ,ilu Rhode Island ni mo fi se ibugbe . Odun kokonla ree ti mama mi ti ku , mo si nife mama mi gan idi niyi ti mo se wu oku won wa si ile mi ti mo sese ko .Ohun iyanu ti mo tun ri nigba ti won wu oku mama mi nipe bi won se sin won lati odun kokonla ni won se wa”.gege bo se so.
Lati ojo kejila osu kejo odun 2023 ti Baale Adeyemi ti di Oba ti won yan ni ilu keesan orile ni idagbasoke ti n ba ilu keesan orile.
Baale Adeyemi je okon lara awon alagba ati alaga awon to n dari ijo Genesis Global Ministry ti Pasito Israel Oladele Ogundipe dasile nileyi ati ni oke okun ti olu ile ijosin won fikale si ilu Eko.




