Omooba Rasheed Adewusi Seto ironilagbara fawon akosemose atawon Agbe to din die loodurun 300 ni ipinle Ogun.

Oni ojo kini osu keta odun egbaa odun o-l-e marundinlogun yi ni omooba Rasheed Adewusi ti opo awon eeyan mo si Praada fa irinse le awon odo akose mose to din die ni oodurun 300 naa lowo, be ni won si tun seto ironilagbara fawon Agbe ati awon Abileko ni woodu mereerin to wa ni Abe Ketu Konstituensi ll .
Awon ise ti awon akosemose naa ko ni ise Amunidara, Weda ati awon to n se Solar Iyen ina to n lo Oorun fi sise .
Leyin ti won fa iwe eri ati irinse le awon ti won ti kosemose naa lowo tan, ni omooba Rasheed Adewusi tun fun awon Agbe ni Opolopo Ada ati Ajile pelu awon nnkan ti won fi n fun oko.
Leyin naa lo wa fun awon Abileko ni Gaasi idana.

Ayeye naa to waye ninu ogba ile Eko Alakobere ljoba ibile Ariwa Yewa to wa ni agbegbe oja ilu ijoun .
Ninu Oro re: Omooba Adewusi ni “mo riipe Olorun da awa eeyan kale maa ran ara wa lowo ni, idi niyen ti mo se bere eto ironilagbara yi fawon eeyan”.
“Gbogbo awa ti a ba ti n rije to si n seku lo ye ka ma ran awon mii lowo, ko ye ka maa wo wo mo nnkan ta ba ni”.
“Looto opo ma n ro pe ljoba nikan lo ye ko pese awon nnkan to ye fun araalu amo mo fe ka mo pe ona po fawon Ijoba wa. Idi niyen to se ye ki eni kookan wa ma ran awon to ba ku die kaato fun lowo lagbegbe wa.”
O wa ro awon Abileko to gba Gaasi Idana naa lati ma lo daadaa tori eyi nikan lo ma ran won lowo lati mase nipin ninu akoba ti eefin ina igi n se fawon eeyan.
Adewusi ni oun ko gbe igbese naa lati wa Ipo Oselu kankan amo ti awon olugbe ketu tabi lpinle Ogun ba pe oun lati wa soju won oun setan lati se bee.
Rasheed gboriyin fun Seneto Olamilekan Adeola Yayi ati Onorebu Gboyega Nasir Isiaka pelu awon ti won n soju Ketu ati iwo- Oorun ipinle Ogun lapapo ninu Egbe Oselu APC bayi.
O ni” looto ori Ayelujara ni Mo ti maa n ri opo awon ise idagbasoke ti won n se nigba ti mo wa loke okun amo ni bayi mo ti fi oju rii lati igba ti Mo ti de pada si Naijira.
Be ni igbakeji Alaga Ijoba ibile Ariwa Yewa
Onorebu llori to wa soju fun eni to je Alaga Ijoba ibile naa Dokito Olusola Samuel Akinbode ati Alaga Egbe Oselu APC ni Ariwa Yewa Onorebu Adeosun Gboriyin fun Omooba Adewusi Praada fun igbese to gbe nipa fifi awon odo senu ise ti olukuluku won fe to si ra irinse fun won nigba ti won setan.
Oloye Adeosun Adekunle to je Alaga Egbe Oselu APC ni Ariwa Yewa ni inu oun dun bi Omooba Adewusi ti ko si nipo Oselu kankan ri se n Seto ironilagbara fawon eeyan lagbegbe naa .”
“Niwon igba ti eni ti ko si nipo Oselu kankan n seto ironilagbara loorekoore fawon eeyan idaniloju wa pe ti iru eni be ba wa nipo o ma se ju be lo. Gbogbo nnkan ti won ba si fi ran an si araalu lo ma fi jise”.
Alaga wa ro awon ti won gba awon ebun naa lati ma fi sise ki won ma se ta rara.
Onijoun ti ilu ijoun Yewa ,Oba Ogunji naa dupe lowo Omooba Adewusi Rasheed fun igbese to gbe lati ran awon odo ati awon Agbe ati awon eeyan mii lowo.
Kabiesi ni ” looto a ma n lo sibi eto ironilagbara ti won ma n se fawon eeyan amo awon to ba wa nipo Oselu nikan lo ma n se e .Sugbon oun to je Iyalenu fun mi nipe Rasheed Adewusi ko si nipo oloselu kankan rara amo o n Seto ironilagbara fawon eeyan”. Mo dupe lowo e gan.an.
‘Mo ri i pe o ti fi apeere to dara lele, to ba le wa se Oselu awon eeyan ma gbadun e gan an ni.
Omidan Ajibode Elisabeth Oluwapelumi to wa lara awon akosemose to gba Masinni iranso lati ilu oja odan ni” tipe tipe lo ti n wu mi lati lo kose aso riran , idi niyen to se je pe bi mo se gbo pe Omooba Adewusi Rasheed fe ran awon odo to ba fe kose lowo ko si ra irinse fun won ni mo se tete lo anfaani yen lati fi ko o, ni bayi mo ti pari ise mi, won si ti ra irinse fun mi bayi, mo dupe lowo won gan an ni loruko emi ati awon akegbe mi toku taajo kose ti won si fa irinse le lowo loni.
Awon mii ti won tun wa nibi Ayeye naa ni : Akowe Ijoba ibile Ketu, ati gbogbo awon asoju Egbe Egbe Oselu APC ni woodu mereerin to wa ni ile Ketu patapata pelu Alhaji Akinyemi Lukmon Temitope SLG Yewa North,ono. Adegbite Moses,Ono, Adeshi Mathew ati
Ono. Akinosi pelu
Onorebu Kokumo.Awon mii to tun wa nibe ni
Ono. Fálọlá Gabriel,
Ajinhinrere Fatumbi Mathew,
Ono. Victor Olayode ati Local Government Women leader Abileko Ogunola Folasade,
Oloye Olayode wuliems ati Oloye Olaleye Emmanuel Alani (JP) Adele Oba ilu ijoun. Iroyinyewa.ng




