ÒṢÈLÚ

Aare Bola Tinubu ma a pari opopona Eko si Sokoto ko to di odun 2031-Sen.Adeola Yayi

Seneto Solomon Adeola Olamilekan Yayi ti fi da awon eeyan loju pe ijoba aare Bola Tinubu ma Pari opopona Eko si Sokoto ko to pari  ijoba re lodun 2031.

Adeola soro yi nibi eto idibo ijoba ibile to n waye jakejado ipinle Ogun loni ojo kerindinlogun osu kokonla odun 2024.

O ni ” mo ni idaniloju pe gbogbo awon ipinle mejeejila ti opopona naa gba koja ni eto oro aje won tun ma ru gogo sii ti won ba pari ona naa.

Seneto Adeola ni looto eto idibo ijoba ibile si n lo lowo amo oun nigbagbo pe egbe oselu APC lawon eeyan ma dibo fun.Be lo fi da awon alaga ati kanselo to wa ni ijoba ibile maraarun to parapo di iwo- oorun ipinle Ogun loju pe oun maa fowosowopo pelu won ki mudunmudun ijoba le dele doko.

Seneto Solomon gboriyin fun ajo eleto idibo ijoba ipinle fun igbese ti won gbe nipa gbigba awon eeyan laaye Lati lo awon kaadi mii bi i: NIN,ati kaadi iwako lati fi dibo, ko ma baa si pe enikeni ko ni kaadi lati dibo.

O tesiwaju pe o seese kawon omo ile igbimo asofin gbe oro naa yewo ti won ba fe sise Lori ofin ti won fi da eto idibo sile.

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button