ÌSÌN
Gbadebọ Rhodes-Vivour di Ọbalẹfun ijọ oloriṣa parapọ agbaaye

Oludije dupo gomina Eko labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour Party,Gbadebọ Rhodes-Vivour lawọn ijọ oloriṣa parapọ agbaaye fẹẹ ja ewe oye le lori gẹgẹ bi Ọbalẹfun aṣoju alaafia lagbaaye.
Ọjọ kejila oṣu kẹrin odun yii ni ayẹyẹ oye naa maa waye ni Ayabot hotels and Events lojuna Ado Odo nilu Badagry nipinlẹ Eko.
Ṣaaju akoko yii ni oloṣelu naa ti sọ pe,oun nigbagbọ ninu nnkan to ba nii ṣe pẹlu aṣa ati iṣe.
