Nnkan de awon Adari Ile eko Ijoba ati Aladani ti n be ijoba ipinle Ogun, won ni ki won ma fagile ayeye ikekogboye awon akeko.

Ni kete ti ijoba ipinle Ogun ti Fi Iroyin sita pe ki Ile eko Ijoba ati Aladani fagile ayeye ikekogboye fawon akeko Jeleosinmi ati awon mii lokan awon Adari Ile eko Ijoba ati Aladani ko ti bale mo ti won si ti n lo be kọmíṣanà fun eto eko lori oro naa.
Ti e o ba gbagbe ko ni ju ose melo kan tawon Ile eko a ma se ayeye ikeko gboye jade fawon akeko won bayi amo Iroyin kan ti kọmíṣanà fun eto eko Fi sita to da awon Ile eko lowo ko lati ma se se awon ayeye bee fawon Ile eko ti ko tii tojubo ti da wahala sawon oluko lorun bayi.
Kiki awon ti won ba Fe jade Ile eko kefa, ikesan ati ikejila nikan ni ijoba ni ki won se ayeye ikekogboye jade fun, ofe ni won si ni ki won se e.
Lesekese ti Iroyin yi jade la ti gbo pe awon Adari Ile eko ti n lo be kọmíṣanà fun eto eko pe ko jowo ko je kawon se awon ayeye naa.
Won je ko dawa loju pe kọmíṣanà ni kiki ti won ba Fe se e laigbowo lowo awon akeko nikan ni oun ma fowosi pe ki won lo se e, atipe awon to ba jade Ile eko kefa, ikesan ati ikejila nikan ni ki won se fun laigbowo.




