ÈTÒ Ẹ̀KỌ́
Trending

Bi ile eko FPI se di FUTI dara gan-an…o si maa sanfaani pupo fawon akeko ati araalu- Dokita Mukail Akinde

Dokita Mukail Akinde to je rekito ile eko gbogbonise ilaro titi won fi yi oruko naa pada si FUTI iyen ( Federal University of Technology ilaro ) ti je ko di mimo fawon eeyan pe igbese to dara ni ijoba gbe bi won se so ile eko naa di ifasiti.

Dokita Mukail soro yi fawon oniroyin ni ofisi re to wa ninu ogba ile eko naa lojo kokonlelogun osu karun odun egbaa odun o-le marunlelogun yi to je ojo keji ti aare Tinubu buwolu iwe ase ti won fi yi oruko ile eko gbogbonise ilaro da si ifasiti imo ero ti ilaro FUTI.
Akinde te siwaju pe ” odun 1979 ni won ti da ile eko yi sile, ti a si ni ekita 898 ile, to fi han pe a ni ile to to lati gba iyara ikeko ti won ma n lo fun ifasiti).
“Ojo kejilelogun osu kerin odun egbaa odun o-le meji la koko lo soro lori bi won se fe so ile eko yi di ifasiti nile igbimo asofin apapo labuja lasiko ijoba Aare Ana, Muhammed Buhari amo ti oro naa ko yanju titi aare fi setan.”
” Irewesi die bawa nigba ti Aare Buhari ko buwolu iwe naa titi won fi pari eto isejoba won amo inu wa dun nigba ti Aare Tinubu buwoluu ti won si yi ile eko gbogbonise ilaro pada si Ifasiti imo ero ti ilaro FUTI”.
” Bi ile eko  yi se di ifasiti ma tunbo mu idagbasoke ati ilosiwaju ba ile eko yi  ati agbegbe re”.
Tori ijoba ko ni kere lati ma mu awon nnkan amayederun wa si ile eko yi , ti eyi si ma sanfaani fun ilu naa, tori gbogbo ibi ti ifasiti ba wa ni ijoba Apapo ma n moju to daadaa ti mudun mundun ijoba si ma n to ibe daadaa.

Akinde je ko di mimo pe eto oro aje ilu ilaro ati agbegbe re ma ru gogo sii ju ti tele lo, ti eyi si ma pese ise fawon eeyan to po gan-an .
O wa ro awon araalu lati lo anfaani ti won ni yi lona to dara ki ise le po fawon eeyan lagbegbe naa.
Dokita Mukail wa dupe lowo Oba Kehinde Gbadewole Olugbenle Asade Agunloye kerin to je olu ti ilaro Yewa ati olori gbogbo awon lobaloba nile Yewa ati Seneto Olamilekan Adeola Yayi fun akitiyan won lori oro naa ti won ko je ko rewon titi ti ijoba fi yi oruko ile eko gbogbonise ilaro pada si ile eko ifasiti imo ero ti ilaro.
‘Ka sooto olorun lo diidi ran Seneto Olamilekan Adeola Yayi wa si Yewa lati wa gba awon eto wa fun wa. Inu mi si dun bi seneto se n mu awon ileri to se se.’
‘ Te ba gbagbe Seneto Olamilekan seleri pe oun ma so ile Yewa di ilu oyinbo kekere (Small London) te ba si n wo ilu ilaro ati ile Yewa lapapo e ri pe o ti n di ilu oyinbo kekere bayi’.
Paripari re Akinde tun dupe lowo aare Tinubu fawon igbese to n gbe lati mu ilosiwaju ba eto eko ati  orileede Naijiria lapapo .

Igbese ti Aare Tinubu n gbe leka eto eko dara gan.Te ba wo eto isuna odun 2025 nnkan ti won ya soto fun eto eko po gan-an, koda ko fi be si ijoba to ya iru owo be si eka eto eko ri.

“Fun apeere ida 90% lowo to kan ile eko gbogbonise ilaro fi le si iye owo ti ijoba ma n ya soto fun wa lodoodun tele “.

Akinde ni looto awon akeko kan ti n beere  nipa iru iwe eri ti won fe maa  gba bii ti won ba setan boya ND ati HND ni tabi B tech .

Akinde ni gbogbo awon to ti n ba eto eko won lo lati ipele ND si HND bayi ni won si ma pari eka eto eko won ti won si ma gba iwe eri to fihan pe won ti pari etoekowon ni kete ti won ba setan  .
Mukail je ko di mimo pe anfaani kan soso tawon akeko naa ni nipe won le satunse iwe eri won si ti Ifasiti iyen (B.Tech degree ti FUTI ) .
Niti awon oluko, Dokita Mukail Akinde je ko di mimo pe ida 80% awon oluko awon lo ni iwe eri PHD ti won le fi ko awon akeko ile eko ifasiti naa.

O wa fi awon obi naa lokan bale pe awon akeko naa ma ni imo eko to peye.

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button