ÒṢÈLÚ

Aare awon Odo igun mereerin ipinle ogun Riye G4 se ipade,won fenuko lori awon nnkan ti awon Odo maa se fu eto idibo 2027

Ni bayi awon ti won je Aare ẹgbẹ́ awon ọ̀dọ́ lawon agbègbè mẹ́reerin ti won pin awon Odo si ni ipinle ogun, iyen Remo, Ijebu,Yewa,àti Egba ti padepo nilu Abeokuta tiise olu ilu ipinle ogun lati ṣe ipadepo lori igbese ti awon Odo maa gbe ati lati mo bi ajosepo to dan moran ṣe fe wa laarin awon odo lasiko idibo odun 2027 to n bo lona yi.

Ninu Ìpàdé náà ni a ti ri eni to je Ààrẹ awon Odo ti Ẹgba, Ijebu, Yewa, àti Ààrẹ Ọ̀dọ́ Remo .
Ipade naa da lori bi awon Odo se ma sise po ki ife,àlaafia ati isokan le wa laarin awon odo lasiko idibo naa ki won si sisepo fun ìdàgbàsókè Ìpínlẹ̀ Ogun.

Be ni won pinnu láti mú kí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ to wa laarin awon odo nipinle ogun lágbára síi lábẹ́ àkóso RIYE G4 ti a mo si Youth Leadership ti Ìpínlẹ̀ Ogun.

Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ tó ga jùlọ fún gbogbo ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ agbègbè mereẹ́rin to si je pe awon Odo lo ma n ko ipa pàtàkì ju nínú àwọn èeyan tó ń dìbò ní ìpínlẹ̀ náà, awon ẹgbẹ naa wa fenuko lori bi isokan se Fe wa laarin awon odo, won si fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé afi ki awon odo sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn kan lórí àwọn ọ̀ràn tó ní í ṣe pẹ̀lú ọjọ́ iwájú ìpínlẹ̀ Ogun.

Be ni won ni awon ko ni gbà ki oloselu kankan lo ete oselu lati Fi keyin awon Odo sira won mo bi ti tele,Tori awon oloselu ma n lo ogbon naa ki enu awon Odo ma ba ko titi eto idibo Fi ma kọjá.won je ko di mimo pe ete naa je fun Àǹfààní awon oloselu kiise fun ilosiwaju awon odo .

Lẹ́yìn ìjíròrò ẹgbẹ,RIYE G4 Youth Leadership gba àwọn ìpinnu wọ̀nyí wole:

Àkókò Bi won se n pin awa Odo si otooto ní Ìpínlẹ̀ Ogun ti won a si ma lo ede eleyameya nitori Àǹfààní ti won ma n rije nidi oselu ti dopin bayi. RIYE G4 ko ni fayegba iru re mo ati wa nisokan bayi.

Àwọn ọ̀dọ́ ní Ìpínlẹ̀ Ogun ko se foworo seyin to ba kan ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ náà,ti a ba n soro nipa atileyin fun ijoba tiwantiwa,àti ìdàgbàsókè àwùjọ.

Pelu ipa ribiribi ti awon Odo maa n ko leka eto Eko,ise,isowo ati awon eto idagbasoke mii idi niyen ti Aare awon Odo se n sapa lati rii pe ipo to joju lawon Odo ma dimun ninu eto idibo gbogbogbòò ọdún 2027.

RIYE G4 yóò máa bá a lọ láti máa kó gbogbo àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú,àwọn olùdíje, àti àwọn Adari jọ fún àǹfààní àwọn ọ̀dọ́ ní ìpínlẹ̀ Ogun. Àwọn ìpinnu àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ wa yóò jẹ́ èyí tí a gbé kalẹ̀ nípasẹ̀ agbára, ìgbẹ́kẹ̀lé, àìṣègbè, ìwà rere, àti ìfaradà tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ fún ìlọsíwájú àti àṣeyọrí ìpínlẹ̀ wa.

Gbogbo ètò ìṣèlú tàbí olùdíje tó bá fẹ́ dije gbodo satileyin fun àwọn ọ̀dọ́ ní ìpínlẹ̀ Ogun won si gbọ́dọ̀ so awon nnkan ti won ba Fe se fawon Odo,kii si se igbese to ma da iyapa sile laarin awon odo. Àwọn ọ̀dọ́ ní ìpínlẹ̀ Ogun nilo àṣojú tó ní ìtumọ̀ to si ma Fi awon Odo si ipo to joju nínú ìjọ́ba kí ó tó di ìgbà ìdìbò, nígbà àti lẹ́yìn ìdìbò.

Won wa ro gbogbo awọn ọdọ ni Remo, Ijebu,Yewa, ati Egba lati wa ni alaafia, lati pa ofin mọ, ati lati wa nisokan bi a ṣe n tẹsiwaju lati ni ajọṣepọ pẹlu awọn ti o ni afojusun to dára fun awa odo.
Be ni won ro awon Odo lati maa ko ipa to joju ninu eto ijoba tiwantiwa bo se ye lona to ma Fi iyi fun won.

RIYE G4 Youth Leadership tenu mo bi ojutu se ma wa si bi ìṣọ̀kan, eto ìdókòwò, eto ààbò àti ìdàgbàsókè ti ko lopin se ma wa ní ìpínlẹ̀ Ogun.

Be ni won tun pinu lati máa tẹ̀síwájú láti máa gbèjà àwọn ìlànà àti ìdarí tó ń ṣàfihàn ìfẹ́ ọkàn àwọn ènìyàn wa, kí a sì rí ọjọ́ iwájú tó dára fún àwọn ìran tó ń bọ̀.

Be ni Aare awon Odo naa Fi oruko ati awon ero ibanisoro won sile ko le rorun fun awon olugbe ipinle ogun lati maa kan siwon loorekoore.

Onorebu. Adekunle Adewale Rasaq Ààrẹ Ẹgbẹ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Egba- 07032977097

Onorebu. Pastor Okikiola Fayomi Ààrẹ , Ẹgbẹ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Ijebu- 09053615047

Komuredi. Isikalu Olanrewaju Alamu Ààrẹ, Ẹgbẹ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Yewa- 08063108882

Kọmíṣọ́nà Eleda Muyiwa Ààrẹ, Ẹgbẹ́ Àwọn Ọ̀dọ́ Remo- 07032318947

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button