Nnkan ma a yipada leka eto oro aje tijoba ba pase fawon eeyan lati maa ra nnkan taa se lorileede Naijiria-Mukhail Akinde

Rekito ile Eko Gbogbonise ilaro, Dokita Mukhail Akinde je ko di mimo pe Nnkan ma a yipada leka eto oro aje ti ijoba Apapo ba pase fawon eeyan lati ma a ra nnkan ti won n se lorileede Naijiria.(Made in Nigeria)
Akinde soro yi lojo ketala osu keji odun egbaa odun o-le marunlelogun yi fawon oniroyin nibi ipade pelu awon oniroyin to waye ninu ogba ile ise amohunmaworan ti ile eko naa to wa ninu ogba ile eko naa.
Ipade yi je eto ti won fi bere ayeye ikejilelogun ti awon to n keko jade nile eko naa ati ayeye odun karundinlaadota ti won ti da ile Eko naa sile.
Rekito ni bi awon omo orileede Naijiria se n pa nnkan to je ti orileede Naijiria ti, ti won si n lo ra awon nnkan ile okeere wa lara nnkan to n se akoba fun eto oro aje orileede Naijiria.
‘O ye ki ijoba pase fawon omo orileede Naijiria, paapaa awon oloselu lati ma ra awon nnkan to ba je ti orileede Naijiria ‘
‘Idi niyen ta a fi n se gbogbo nnkan to ye lati riipe awon oloselu wa n ra awon ero ta a se nile eko gbogbonise ilaro ti won ba fe seto ironilagbara fawon eeyan wa’.
“Die lara awon ero ti ile eko naa se tawon oloselu le fi seto ironilagbara fawon eeyan ni; Ero to ma n se Kokoro, Ero ti won ma n fi se Fufu ati ero ti won ma n fi yin Agbado pelu Ero ti won ma n fi te Eyin ati bee bee lo”.
“Looto ijoba apapo n pese awon nnkan ti awon akeko wa nilo lati ma fi se idanrawo eko won, amo a maa gbe igbese lati je ki opo awon oloselu wa mo nipa awon ero taa ti se yi ki won le ma ra a fawon eto ironilagbara ti won ma n se fawon eeyan”.
” Mo ni idaniloju pe ti ijoba apapo ba tun ran ile eko gbogbonise lowo ju bi won se n se lo ti won si pa lase fawon olugbe orileede Naijiria lati ma ra awon nnkan ibile wa, o damiloju pe eto oro aje wa maa tunbo ru gogo sii”.
Rekito je ko di mimo pe oga olopa patapata lorileede Naijiria, Kayode Egbetokun ni igbimo to se kokari eto naa yan lati wa soro lori awon Ipa ti igbese ti aare Tinubu n gbe leka eto aabo ati awon eka mii se n mu ilosiwaju ba awon omo orileede Naijiria.
Niti awon ti won fe gba amin eye, Akinde je ko di mimo pe awon aseyori ti opo won se lawon wo tawon fi fun won lami eye naa.




