E yera fun iwa odaran, e lo imo ti e gba ni FPI lati mu ilosiwaju ba orile ede Naijiria – Dokita Mukhail Akinde.

Rekito ile eko gbogbonise ilaro, Dokita Mukhail Akinde ti ro awon akeko egberunmeje lgba odin mewa ti won sese jade ni saa ikeko eleekejilelogun ti ile eko naa, lati yera fun iwa odaran ki won si lo imo ti won gba ni ile eko gbogbonise ilaro lati mu ilosiwaju ba orileede Naijiria.
Akinde soro yi lojokokondinlogun osu keji odun egbaa odun o-le marunlelogun yi nigba ti won n kede awon akeko egberun meje igba odin mewa naa gege bi awon ti won keko jade ni ipele HND ati ND ti saa ikejilelogun ile eko naa ati ayeye odunmarundinlaadota ti won da ile eko naa sile ti won se ninu ogba ile eko naa nilu ilaro tiise olu ile Yewa.
Dokita ro gbogbo awon akeko naa lati tepa mose ki won si bere si ni lo awon imo ti won ti gba lodo awon oluko won ni kete ti won ba ti pada sile. Be lo tun ro won lati yera fun iwa odanran ki won si tepa mose, tori sise eyi nikan lo ma mu ilosiwaju ba orileede Naijiria .
1121 lo je okunrin ninu awon ti won gba oye HND ti 1498 si je obinrin.
Awon okunrin 2180 lo gba oye ND ti awon obinrin si je 2397.
Awon 148 lo se daadaa ju ninu awon to gba ami eye HND .Moses Kehinde Salome to ko imo nipa,(office TechnologyManagement ) lo gba maaki to po ju 3.90 CGPA.
Awon igba ole marun205 akeko lo se daadaa ju ninu awon to gba ami eye ND.Oynyemachi Abigail Ezinne to je obinrin ninu awon akeko to wa ni eka (Science Laboratory Technology) lo ni maaki to po ju, 3.93 CGPA.
Dokita Akinde ni ti awon akeko naa ba n lo awon eko ti won ti ko paapaa awon ti won wa leka imo ero , o ma tunbo je kawon ero ti won n ko wole orileede Naijiria dinku sii.
O ni ” opo awon ero taase nile eko yi ni awon agbe aladanla ti n lo bayi; ile eko yi la ti se ero ti oko OLAM to wa ni Abule Ruubi ni Nasarawa n lo” . Be la tun se opo ero lorisirisi ti awon agbe ati awon ti won ma n se nnkan jije mii le lo.
O ro awon akeko naa lati ni afojusun to dara bii ti awon meteeta ti won fi ami eye felosiipu awoodu da lola : Akoko ni Festus Egwarewa Adeniyi Keyamo to je minisita fun oko oju ofurufu, Abiodun Akanbi Durosinmi ati Alaba Jacob Afolabi .
Akinde ni awon meteeta yi wa nipo ti won wa loni tori won ko ko egbe kegbe won si ni afojusun to dara fun ara won ati orileede Naijiria lapapo.
” Mo ni idaniloju pe ti eyin naa ba yera fun egbe kegbe ti e si tepamose e ma de lpo giga lojo ola”.gege bo se so.
Komisanna olopa ipinle Ogun, Lanre Ogunlowo to soju oga agba olopa orileede Naijiria Kayode Egbetokun je ko di mimo ninu oro re fawon akeko naa pe ki won ma se ni ero pe awon n salo kuro lorileede yi bi won se pari eko won.
” Mo fe je ke Mo pe opo anfaani ni ijoba aare Tinubu ti gbe kale fawon omo Naijiria ti nnkan ko si ni pe dara ti eyin naa ba ti fowosowopo pelu ijoba”.
E ma ni lero pe ti e ba kuro lorileede yi nikan le ma saseyori, tori aare Tinubu ti n gbe igbese ti nnkan fi ma dara gann lorileede yi.
Minisita fun oko ofurufu Festus keyamo dupe lowo ile eko gbogbonise ilaro fun bi won se ka awon meteeta ye si Eni ti won ma fun ni felosiipu awoodu ti ile eko naa. O wa seleri pe oun ati awon to ku ko ni kere nipa sise nnkan ti o ba ye kawon se lati ma mu ilosiwaju ba ile eko naa.
Asoju aare Tinubu ati asoju Gomina lpinle ogun, omooba Dapo Abiodun naa ba awon obi awon akeko naa yo gidigidi won si ro awon akeko naa lati ma gboran si awon obi won lenu.
Awon loba loba to wa nibe ni; Oba Kehinde Gbadewole Olugbenle olu ti ilaro ati olori oba nile Yewa, Olota ti ilu ota pelu opolopo awon lobaloba nile Yewa.
Be ni onisowo ni Alaji Ibrahim Dende Egungbohun ati awon onisowo egbe re wa nibe pelu www.africanewsbroadcast.ng




