OGUN 2027, YAYI dupe lowo Gomina Abiodun fun atileyin re lori Ile Ipolongo ibo ti oun ko silu Abeokuta.

Ese o gbero nilu Abeokuta nigba ti Aṣòfin agba Seneto Solomon Olamilekan Adeola ti Opo mo si YaYi si Ile Ipolongo ibo Alaja merin si ilu Abeokuta tiise olu ilu ipinle ogun lojo kokonla osu keje ọdún Egbaa odun o-le merindinlogbon yi.
Nigbati o nsoro nibe Asofin Agba Adeola dupe pupo lowo Gomina ipinle ogun bayi, Omooba Dapo Abiodun fun bi o se gbà a laaye ti o si tun fowosowopo pelu re lati ko Ile naa.
O ni” Odun keji ree ti a bere Ile yi ni kiko nigba ti mi o tii mo pe emi ni won ma fa kale lati dije si ipo Gomina ipinle Ogun ninu ẹgbẹ Oselu APC. Mo sa n fi okon kan se mo si ni Igbagbọ ninu Ọlọrun”.
” Bi Igbagbọ mi se wa di ooto loni tun n fi mi lokan bale pe Ọlọrun ko ni doju ti wa awa la ma a bori ninu eto idibo to n bo lati ibi Oke-Mosan la n lo lagbara Ọlọrun”.
Be ni Seneto tun dupe pupo lowo gbogbo agba ẹgbẹ Oselu APC, awon Omo ẹgbẹ ati awon lobaloba bi won se ti oun leyin lati wa dije du ipo Gomina ipinle ogun.
Seneto Adeola Soo di mimo wipe Ile naa wa fun gbogbo Omo ẹgbẹ Oselu APC, “Tori lati oni lo ibi la ti fe maa jiroro bi itesiwaju se fe maa ba ẹgbẹ wa titi di igba ti ibo Fi maa pari, ibi lati ma lo si Oke- Mosan lagbara Ọlọrun”.
” Mo ni igbagba ninu Ọlọrun pe o ma se bee”.
Be lo fi da awon Omo ipinle ogun loju pe oun maa tele awon alakale ti Gomina Abiodun n balo ki idagbasoke le maa ba ipinle ogun.

Ogbeni Tokunbo Talabi to je Akowe ljoba lpinle ogun, to soju Gomina Abiodun nibe naa gbe osuba rabande fun Asofin Agba Adeola fun bi o se ko olu Ile ise ipolongo re si ilu Abeokuta tiise olu ilu ipinle ogun.
Talabi so wipe tayotayo loun fi so lokan oun wipe Asofin Agba Adeola ti setan lati tele igbese ti Gomina Abiodun la sile fun idagbasoke Ipinle yi.
Nibi ayeye manigbagbe naa ni a tiri Oloye Yemi Sanusi Alaga Egbe APC lpinle yi to si tun je pe oun lo si Ile Ipolongo ibo naa.
Awon mii to tun wa nibe ni Alhaja Kudrat Adegunwa Balogun igbakeji adije Gomina, Arabinrin Temitope Adeola Aya Adije, Alake tile Egba Oba Adedotun Aremu Gbadebo, Olu Ilaro ati olori oba tile Yewa Oba Kehinde Olugbenle, Olubara tile Ibara Oba Jeccob Omolade awon Omo igbimo Asofin Ipinle ogun ati awon Aṣòfin ni ilu Abuja pelu awon Omo ẹgbẹ Oselu APC ati awon mii.




