ÒṢÈLÚ

Sẹ́nétọ̀ Adeola rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti dìbò fun Aare Tinubu leekeji,ko le pari awon ise ribiribi to n se lowo

Olùdíje sipo gómìnà labe Asia ẹgbẹ Oselu ti (All Progressives Congress) ni Ipinle Ogun, Sẹ́nétọ̀ Solomon Olamilekan Adeola, ti opo mo si YAYI tí ro gbogbo awon Omo orileede Naijiria lati dibo Yan Aare Bola Ahmed Tinubu leekeji.

Seneto Adeola soro yi nigba to n ba awon oniroyin soro leyin to dibo Aare tan ni woodu akoko to wa ni Pahayi nilu ilaro tiise olu Ile Yewa, ni ipinle Ogun.

Adeola ro awon Omo orileede Naijiria ati awon olugbe ipinle Ogun lati dibo won fun Aare Bola Ahmed Tinubu.

Niti Iwo-Oorun ipinle Ogun,Seneto ni” mo ro gbogbo eyin olugbe Iwo-Oorun ipinle Ogun, ejowo eje ka dibo wa fun Aare Tinubu.Ti a ba wo awon ise idagbasoke ti won n se lowolowo bayi paapaa opopona Sokoto si Badagiri ti won n se lo lowo to ma mu idagbasoke to lamilaaka ba agbegbe wa”.

Sẹ́nétọ̀ Solomon Olamilekan Adeola (YAYI)  wa ro àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú to wa ni Ile Yewa pe ki won wà ní ìṣọ̀kan kí wọ́n sì jẹ́ kí ẹgbẹ Oselu APC tẹ̀síwájú.

Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ, a kò gbọdọ̀ fún àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ní àǹfààní láti ri ibo kan soso to ba ti di asiko ibo lati ori eto idibo Aare titi de ori eto idibo Gomina ati Omo Ile igbimo Aṣòfin ipinle Ogun.

“Mi o Fe ka gboruko ẹgbẹ Oselu mii lagbegbe wa a Fi ẹgbẹ Oselu APC. Àwọn ènìyàn wa gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́ àti olùfọkànsìn fún ẹgbẹ́ náà,” ni ó wí.

Adeola kìlọ̀ fún àwọn olùtìlẹ́yìn ẹgbẹ́ òṣèlú náà pé kí wọ́n má jẹ́ kí àwọn olóṣèlú láti ẹgbẹ́ òṣèlú alatako tàn wọ́n jẹ, ó ní àwọn kan lára ​​wọn ti jẹ́ àǹfààní láti ọ̀dọ̀ APC tẹ́lẹ̀ kí wọ́n tó fi ẹgbẹ́ òṣèlú náà sílẹ̀ nítorí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ àti ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan lo je ki won lo sinu ẹgbẹ mi i. Ti e ba ri won e bere awon nnkan ti won se nigba ti won wa nipo.”

“Wọn ma  wá ba yin pe ẹgbẹ  ADC, PDP tàbí ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn sàn ju APC lọ. E Má ṣe gbọ́ tiwọn. Àwọn kan lára ​​wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ipò òṣèlú lábẹ́ ìdarí Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, ṣùgbọ́n lónìí wọn kò ní ohunkóhun tó ní ìtumọ̀ láti fún àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà,” gege bo se sọ.

Seneto Solomon Olamilekan wa menukan die  lára ​​àwọn àtúnṣe ti Aare Bola se latigba to ti di Aare orileede yi.lara re ni  ìyọkúrò owó ìrànlọ́wọ́ epo, àtúnṣe owó orí àti ètò eyawo fawon akeko to a mo si  NELFUND, ó sì fi kún un pé àwọn ẹgbẹ́ alátakò pàápàá ti gbà pé àwọn ìlànà náà bojumu bi Aare se gbe kale.

Be ni Adeola tun menu ba títí  Sokoto-Badagry Super Highway àti Lagos-Calabar Coastal Highway, ó sì ṣàpèjúwe wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ àkànṣe àgbáyé tí ó lè mú kí ọrọ̀ ajé pọ̀ sí i káàkiri orílẹ̀-èdè Naijiria.

Ó je ko da awon eeyan loju pe Ààrẹ Tinubu màa ṣètìlẹ́yìn fún ìṣàkóso oun tí óun bá di gómìnà  Ìpínlẹ̀ Ogun, Tori Aare Bola ko Fi oun sile lawon igba ti oun wa nilu eko se ni won duro ti oun bi Baba si Omo  nínú iṣẹ́ òṣèlú rẹ̀ láti ìgbà tí ó ti wà nínú òṣèlú Èkó.

Seneto Solomon je ko di mimo pe Nàìjíríà maa  rí ìdàgbàsókè àti ìdúróṣinṣin tó ga síi tí wọ́n bá tún yan Ààrẹ Tinubu ní ọdún 2027.

Paripari re o dupe lowo awon Gomina tẹlẹri ni ipinle Ogun Baba OluSegun Osoba,  Seneto Gbenga Daniel ati Seneto Ibikunle Amosun fun bi won se gbaruku tii ti won si je ko rorun fun un lati di eni ti won fa sile lati dije gege bi Gomina ẹgbẹ Oselu APC ninu eto idibo to n bo lodun 2027.

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button