Omooba Segun Adewale, to dije fún ipò gómìnà tẹ́lẹ̀, ti n Satileyin fun Seneto Adeola Yayi to n dije fun ipo Gomina ninu ẹgbẹ Oselu APC lọdún 2027.

Omooba Segun Adewala ti Opo mo si (OSA) to dije fún ipò Gómìnà ní Ìpínlẹ̀ Ogun tẹ́lẹ̀,, ti bere si ni ko awon eeyan jo lati se atileyin fun Seneto to n soju Iwo-oorun ipinle ogun lowo bayi to si fe dije fun ipo Gomina labe Asia ẹgbẹ Oselu APC ninu eto idibo to n bo lodun 2027.
Iwe Iroyin Yewa ròyìn pé omooba Segun Adewala ti n ko awon eeyan jo jakejado Iwo-oorun ipinle ogun ko le seese fun Seneto Solomon Olamilekan Adeola YaYi ti ẹgbẹ Oselu APC lati jawe olubori ninu eto idibo naa.
Ninu ojo weli-weli to n ro ni Omooba Segun Adewala de si woodu keta ni ilu ilaro pelu Bana ti won ya foto oun ati Seneto Adeola YaYi si lara to ni akole naa ( OSA For YAYI ) o si fi han pe gbogbo ara ati emi oun loun fi n Satileyin fun Yayi

Ni bayi gbogbo awon ẹgbẹ Oselu PDP to wa ni Guusu Yewa lo ti gbà lati sise pelu omooba Segun Adewala ki Seneto Solomon Olamilekan Adeola YaYi le bori.
Omooba Adewale ni Ibo ti a Fe di yi Ibo Alajobi ni, o wa ro awon eeyan ki won dibo Alajobi fun YaYi.
“E ma gbagbe pe Ile Baba YaYi ni ibi,ti a ko ba gbaruku tii awon Ile iya re ma gbà lowo wa”.
“A Fi ka pawopo fi ibo gbe YaYi wole, tori oju ko gbodo tiwa ni Yewa bii ti Tele”.
Omooba Segun je ko da awon to wa ni woodu keta ni ilaro loju pe bi oun se wa si woodu won loun ma lo si gbogbo woodu to wa ni Iwo- oorun Ipinle ogun patapata”.
Leyin naa lawon eeyan to wa ni woodu keta ba omooba Segun Adewala ya foto ti won si fi daa loju pe digbi lawon wa leyin re .
Adewale Fi orin senu pe o ti to asiko fun Omo Iwo-oorun Ipinle ogun lati dari ipinle ogun be ni Seneto Solomon Olamilekan lo ma se tori oun lo kajue to si le se e .
Omooba Segun Adewala tẹnumọ́ pé inú òun dùn láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn to n Satileyin fun Yayi ko le de ipo Gomina ipinle ogun labe Asia ẹgbẹ Oselu ( All Progressives Congress (APC) .
Paripari re omooba Segun Adewala wa fowosoya pe oun mo daju pe Seneto Solomon Olamilekan Adeola lo ma jawe olubori ninu eto idibo to n bo lodun 2027.




