Omooba Segun Adewale darapo mo Alajobi to n sagbateru fun Seneto Solomon Olamilekan YaYi lori ibo odun 2027

Omooba Segun Adewale ti Opo mo si OSA ti darapo mo ẹgbẹ kan tawon Omo Iwo-oorun ipinle ogun kojo lati se atileyin fun Seneto Solomon Olamilekan Adeola YaYi ki awon eeyan le dibo Alajobi fun un ninu eto idibo to n bo lodun 2027.
Ẹgbẹ yi ni Awon Omo Yewa-Awori kan da sile ti a si ri Omooba segun Adewale naa laarin won ti won jo ya foto to si n fi dawon loju pe oun naa maa Satileyin fun won to ba ti je nitori ki Seneto Solomon le de ipo Gomina ipinle ogun lodun 2027 ni won se ko o jo.
Bi eto idibo sipo Gomina odun egbaa odun ole metadinlogbon 2027 se n sun mole ni oro kan n tan kale pe ibo Alajobi ni ki won Fi ibo Gomina ipinle ogun di.
Bi ojumo se n mo ni ẹgbẹ kan ti awon Omo Yewa-Awori gbe kale ti a mo si ẹgbẹ ibo Alajobi ti n polongo kaakiri Iwo-Oorun ipinle ogun pe ki won je ki awon di ibo Alajobi fun YaYi.
Bi won se n lo si awon woodu tawon oloselu ti n se ipade oselu won, ni won tun n lo lati ojule si ojule lati maa salaye fawon eeyan lati je ki won mo idi to se ye ki won wa nisokan ki won si di ibo Alajobi fun YaYi.
Ki ni a n pe ni Ibo Alajobi gan-an?
Ninu asa Yoruba,Alajobi tumosi awon eeyan ti won wa ninu ila idile kan naa tabi ti won jo dagba papo ni adugbo tabi ninu ilu tabi agbegbe kan naa.
Iru awon eeyan bee gbodo maa duro ti Ara won nigba gbogbo to tumosi pe isokan gbodo wa laarin won ki won si maa gbaruku ti Ara won lasiko ti enikan ba wa ninu isoro tabi lasiko ti nnkan Ayo ba kan enikan ninu won . Ti a ba si wa ri enikan ti ko se bee, ibe ni oro naa “Alajobi a daa ti ma n jade”.
Idi niyen ti awon ẹgbẹ yi se mu Alajobi wo inu oselu, to si n se ilaniloye fawon eeyan nipa re, idi to se ye ki won di ibo Alajobi fun Seneto Olamilekan Adeola YaYi ninu eto idibo 2027.
Gege bi ojulowo Omo bibi Iwo-oorun ipinle ogun ati Olugbe agbegbe naa lokunrin ati lobinrin won gbodo wa nisokan ki afojusun won ni 2027 le te won lowo.
Ki nidi ti a se nilo ibo Alajobi ni Iwo-oorun Ipinle ogun?
Latigba ti won ti da ipinle ogun sile ni awon eeyan to wa ni Iwo-oorun Ipinle ogun ko ti fi bee je mudun-mundun eto ijoba daadaa bi awon igun meji to ku iyen Egba ati Ijebu. Yato si iyen ko tii si Omo Iwo-oorun ipinle ogun to ti di Gomina ri.
Idi niyen ti eto idibo 2027 se je nnkan to mu-mu laya awon olugbe Iwo-Oorun ipinle ogun, Tori asiko yi nikan ni Àǹfààní wa fun won lati ni eni to ma a se Gomina to maa je Omo bibi Iwo-oorun ipinle ogun ti eyi si ma pa egun atodun modun to n ba awon eeyan naa finra re, ni ti pe won ko tii ni eni to de ipo Gomina ri .
Idi niyen ti Alajobi se n ro gbogbo awon Omo ati olugbe Iwo-Oorun ipinle ogun pe ki won jowo, ki won ma tun je ki ife imotara eni nikan leka eto oselu tun da ipinya sile laarin won mo, ki gbogbo won sise si ojukan naa Tori owe Yoruba ni ” ti a pa ito po, ito ma ho” .
Be ni Alajobi tun ran won leti pe ki won ma je ki Àǹfààní to wa Nile yi tun fo awon ru , looto eto idibo ma wa o si ma lo, nnkan ti awon ba se lawon ma pada bo wa ba, Tori Àǹfààní ipo Gomina yi le ma tun Tete wa si Iwo-oorun ipinle Ogun mo.
Idi ti oro Alajobi se koja oro oselu to si da lori asa ati ise wa niyen.
A ko da Alajobi sile lati da ipinya si aarin awon olugbe Iwo-Oorun ipinle ogun.
A daa sile lati fi mu won ranti awon Asa won ati awon nnkan to pawapo ni .Tori gbogbo ijoba ibile maraarun to parapo di Iwo-oorun ipinle ogun, lati ijoba ibile Imeko-Afon, Ariwa Yewa, Guusu Yewa ati Ipokia pelu Ado-Odo Ọta ni ibasepo, itan idile ati eto igbeyawo pelu asa ati ona ti won gbà n se nnkan jora won.
A gbe Alajobi kale ko le ran awon eeyan leti pe ikan naa ni wa ti eyi si gbodo mu wa ranti nnkan to ye ka se ati ibi to ye ka lo.
Ki nidi ti a se nilo ibo Alajobi?
Ibo Alajobi duro fun :
:Ibo ti a ma di si oju kan laisi ipinya
:Idibo ti a maa di nitori Àǹfààní awon to ku
kiise nitori Àǹfààní ti awa nikan .
: Idibo to maa Fi han pe ko si ipinya laarin wa ni Iwo-oorun Ipinle ogun.
:Ibo to ma a fun wa lagbara lati ri nnkan ta a fe gbà ninu ipo oselu ipinle ogun.
:Ibo yi la nigbagbo pe o maa ṣàtúnṣe ojo iwaju awon Iran to n bo leyin ola.
Ti gbogbo wa ba di ibo wa si ojukan kii se fun Àǹfààní Seneto Olamilekan Adeola YaYi nikan, o maa tun fi han lojo iwaju pe looto ni a n se nnkan papo ti a si wa nisokan ni Iwo-oorun ipinle ogun.
Ni soki nnkan ti a Fe ka mo nipa ibo Alajobi nipe, a baa je Agbalagba lokunrin tabi lobinrin, omowe,oniṣẹ Owo, Agbe ati Onisowo tabi Akeko ati gbogbo awon to wa lokeere a fe ka sise papo ka si je ki isokan wa laarin wa.
Ti a ba n soro nipa imo ogbon ori , ti awon eeyan ba wa ni isokan lo ma n je ki won Tete rowo mu nidi oselu ki ilosiwaju si ba agbegbe won.
Mo Fe ka ranti pe ebi kan idile kan niwa ki oselu to de, ka ma si gbà ki oselu to de pinwa niya.
Àwọn olùwòye òṣèlú sọ pé àwọn èeyàn sábà máa ń borí ìdìbò nígbà tí won bá ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn kan. Èyí je ìdí tí ẹgbẹ́ Alajobi fi ń tẹ̀síwájú láti fún àwọn ènìyàn níṣìírí láti máa bá àwọn ọ̀dọ́, ẹgbẹ́ olọja, àwọn ẹgbẹ́ ìdàgbàsókè àwùjọ, àwọn ẹlesin ibile, ẹlesin kirisiteni ati musulumi àti àwọn ògbóǹtarìgì sọ̀rọ̀.
A ni Igbagbọ pe ti a ba wa niṣọkan o maa je ka ni agbara lati le fi ibo wa so ohun ti a ba fe.
Nínú ìtàn ìpolongo Ibo Alajobi,gbé Sẹ́nétọ̀ Solomon Olamilekan Adeola (Yayi) kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oju sun kan soso ni ogun, ti ipo Gomina ti a n fe ni Iwo-oorun Ipinle ogun fi le tewa lowo.
Be la tun ṣàpèjúwe ìdíje rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí asiko to daa ju to si ye ki gbogbo wa gbaruku tii ka le jawe olubori ki awa naa le ba ẹgbẹ pe leka oselu.
Yálà gbogbo àwọn olùdìbò fara mọ́ èrò yẹn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, kò sí iyèméjì pé Alajobi ti se nnkan ti a le se lati polongo ihinrere nipa YaYi fawon eeyan pe oun nikan ni ki won dibo fun ninu eto idibo to n bo lodun 2027.



