Eso asobode fa Milionu meje owo sefa to je Milionu metadinlogun owo naira le ajo EFCC lowo nipinle Ogun

Oga agba ajo eso asobode nipinle ogun Kontirola Muhammed Shuaibu ti fa Milionu meje owo sefa to je milionu metadinlogun ti won ba se e si owo orile ede Naijiria le asoju ajo EFCC, ogbeni Oguzi Moses A. To n dari eka to n sewadi lodo ajo EFCC to tun je igbakeji komanda ajo naa ni Ipinle Eko ni Zone 2 lowo .
Oni ojo karundinlogbon osu keta odun egbaa odun o-le marunlelogun yi ni Kontirola Muhammed Shuaibu to n dari iko asobode to wa ni idiroko fa owo naa le ajo EFCC lowo ninu ofisi re to wa ni idiroko.
Shuaibu ni, ise asekara tawon osise asobode n se ati bi won se n sise lai dabo lo je ki won ko firi apo ti won fi di owo naa nibi ti won gbe si.
O je ko di mimo pe looto eni to gbe owo naa ti salo amo owo naa lawon ti gbe tawon si ti n fimu finle lati mo iru eni to n sise naa .
O so pe,”A sise pelu ofin Naijiria to so pe enikeni to ba gbe owo to ba koja dola mewa ni won gbodo fihan ajo eso asobode ki won to ko koja lenu bode. Sugbon nigba ti eni to ni owo naa ko ti fi han ajo asobode iru eni bee ti se si ofin niyen”.
” o ni owo ti ko to milionu mewa dola nikan ni anfaani wa fun lati gbe koja amo eyi to ba ti pe milionu mewa tabi to le si owo naa ni o ti di ofin to si ye kiru eni be fihan lenu bode”.
Shuaibu gboriyin fawon osise to mu owo naa o si fi dawon loju pe oun ko ni figba kankan gba awon to ma n se fayawo owo laaye lenubode idiroko.
Ogbeni Oguzi Moses to tewogba owo naa lowo kontirola Shuaibu gboriyin fun ajo eso asobode fun ise takuntakun ti won se lati mu iru owo bee.
Moses tesiwaju pe ajo EFCC ma lo sayewo owo naa lati mo boya ojulowo ni tabi gbarogudu.




