Kontirola James ojo ti fa oogun oloro ti won gba lowo awon onifayawo le ajo NDLEA lowo

Kontirola James Ojo to n dari eka akoko ajo eso asobode nipinle Ogun ti fa oogun oloro to le ni egberunmeje le ajo to n gbogun ti oogun oloro NDLEA lowo.
Oni ojo eti ,ojokejilelogun osu kokonla odun 2024 yi ni eso Asobode eka akoko nipinle Ogun fa awon oogun oloro naa to le ni egberunmeje igba ole metadinlogun ati eyo meje kilogiramu 7,217.7 le ajo to n gbogun ti oogun oloro NDLEA lowo.
Kontirola Jamisi Ojo je ko di mimo nigba to n fa awon oogun oloro naa le ajo to n gbogun ti oogun oloro lowo pe, kilogiramu lgbo egberunmeje ole igba meji lo wa ninu awon oogun oloro ti awon fa le ajo ti o n gbogun ti oogun oloro lowo.
Be lo tesiwaju pe Paaki oogun oloro oodunrun ole ogota ati eyo meji 362 lo tun wa nibe ,ti Aropo owo ori oogun naa si je #117,587,405.00.
Ojo je ko di mimo pe awon oja yi ni awon eso asobode gba laarin ojo ketala osu kewa si ojo kejila osu kokonla .
Ajo eso asobode gba awon eru naa lagbegbe Abeokuta ati Agbawo/Igankoto ni agbegbe Ariwa Yewa ni ijoba ibike Imeko-Afon , ipinle Ogun.
Ojo ni oun ko ni gba awon onifayawo laaye lati ma ko oogun oloro wole si orile ede yi, tori o n se lpalara to po fun ilera awon eeyan.
Gbogbo awon oogun oloro naa ni Kontirola ojo ti fa le adari ajo to n gbogun ti oogun oloro ni agbegbe ldiroko lowo.
Ogbeni Olusegun Adeyeye to je adari awjo ti o n gbogun ti oogun oloro NDLEA je ko di mimo nigba to tewogba awon oogun oloro naa pe gbogbo Iwadi to ba ye ni awon ma se Lori oogun na.
Kontrola Jame ni atileyin ti Kontirola Bashir Adewale Adeniyi fun iko naa lo je ki won se aseyori naa lasiko yi.
Kontirola ojo no ajo naa ko ni kere lati maa gbogun ti awon onifayawo ki won ma ba raye doju eto aabo orile ede yi ru.
O wa to awon omo orile ede Naijiria lati fowosowopo pelu ajo eleto aabo ko le rorun fawon lati kapa awon ti won an owo fayawo laayo




