ÌṢÒWÒ

Maa riipe opin de ba ise fayawo ni ipinle ogun-Kontirola Muhammed Shuaibu

Kontirola Muhammed Shuaibu ti je ko di mimo pe oun ma mu opin de ba ise fayawo nipinle Ogun.
Shuaibu soro yi loni ojo isegun ojo kewa osu kejila odun 2024 ni kete to gba opa ase lpo adari ajo eso asobode eka akoko nipinle Ogun.

” Ma a ran awon ti won ba fe ma sise lona to ba ofin mu lowo ki ise won le ma a lo daadaa, amo mi o ni fayegba awon to ba fe ma keru wole lona ti ko ba ofin mu”

Ni kete ti Muhammed gba opa ase adari awon eso asobode eka akoko nipinle Ogun lowo Kontirola Jamisi Ojo to feyinti lenu ise,  leyin to ti lo odun marundinlogoji lenu ise gege bi osise ajo asobode lorile ede Naijiria.

Shuaibu to ti figba kan je adari eka kan ti won n pe ni  (Joint Border Patrol Team 2 )  amo ti won ti tuka bayi ni, oun ma lo awon iriri ti oun ni lasiko ti oun n dari awon iko naa lati mu nnkan to lawon enubode to wa nipinle Ogun.

O je ko di mimo pe awon irir ti oun ni naa ni oun ma lo lati fi se opo ise ni ipinle ogun.

O wa ro gbogbo awon eso alaabo to ku ti won wa ni ipinle Ogun lati fowosowopo pelu ajo eso alaabo kositomu ko le rorun fun won lati saseyori .
Be lo ro awon lobaloba ati awon asaaju ilu lati fowosowopo pelu oun bi won se fowosowopo pelu Kontirola Jamisi Ojo to n feyinti lenu ise .

Be ni Kontirola ojo naa ro awon lobaloba ati gbogbo awon ajo eleto aabo toku lati gbaruku ti Kontirola Shuaibu bi won se gbaruku ti oun nigba ti oun wa lenu ise gege bi Kontirolato n dari eka akoko nipinle ogun.

Awon mii ti won tun wa nibi ayeye naa ni asoju ajo to n gbogun ti oogun oloro nipinle Ogun (National Drugs Law Enforcement Agency’s),Army, Olopa,Imigirasion ati awon mii pelu awon asoju orile ede ile olominira Benni.

Related Articles

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Back to top button