Ayajo ojo awon Asobode, Kontirola Shuaibu Seleri lati mu sikani masinni to n sayewo eru to wa ni idiroko soji pada .

Kontirola Muhammed Shuaibu to n dari iko asobode to wa ni eka akoko nipinle Ogun, iyen Ogun 1komand ti seleri pe oun maa riipe Sikani masinini (Scanning Machines) to n sayewo awon eru ti won n ko wole ati eyi to n jade lorile ede Naijiria wo daadaa.
Shuaibu soroyi nibi ayeye ajodun ayajo ajo eso asobode lagbaye ti odun egbaa odun o-le marunlelogun yi, to waye ni oni ojoketadinlogbon osu keji odun yi ni ofisi re to wa ni idiroko nipinle Ogun.
Muhammed ni, gbara ti oun gbase gege bi oga agba ajo eso Asobode eka akoko nipinle Ogun ni oun ti lo sayewo masinini naa ti ijoba fi owo rogunrogun se si enubode to wa ni idiroko, ti oun si ti oinu pe masiini naa ma bere ise pada laipe.
Bo ti le je pe die lara idi ti ero naa ko se sise mo ni pe opo awon ti won ko ni bi won se n lo masinini naa ni won ti feyinti lenu ise asobode, ti ise si ti gbe awon mii ti ko tii feyinti kuro ni ipinle Ogun.
O tesiwaju pe oun ko ni kere lati maa gbogun ti enikeni to ba yan ise fayawo laayo gege bi awon ti n se tele .
Igbakeji kontirola Clement Amawah to soro nipa ayajo ojo awon kositomu je ko di mimo pe ajo naa ti n gbe opo igbese lati ma sise asobode lona ti igbalode ki ona ti won gba n pawo wole le tunbo rorun sii.
Lara igbese ti won gbe nipe won ti n seto eka kan to n je e-Customs, single window platform ati beebee lo.
O salaye pe awon eka yi ma je ko tunbo rorun fawon onisowo lati se gbogbo iwe won ki won si san awon owo to ba ye sapo ijoba lowokan lai mu wahala dani rara.
Ogbeni Borny to je asoju orile ede olominira Benin dupe lowo awon kositomu fun akitiyan won lati rii pe irepo wa laarin orile ede Naijiria ati orile ede olominira Benin.
O wa ro oga agba ajo eso asobode lorile ede Naijiria , Kontirola Adeniyi lati se gbogbo nnkan to ye ko se ki eto oro aje laarin orile ede Naijiria ati orile ede olominira Benin le tunbo rorun sii.
Lara awon eso alaabo to wa nibi ayeye naa ni, Asoju ajo Otelemuye, Olopa , Sifudifensi pelu awon eso alaabo to ku.




