Eso Asobode idiroko gba eru fayawo to le ni ₦4.6bn láàrín ọjọ́ metalelogorin, wọ́n sì pa #259.2m wole sapo ijoba apapo

Ilé Iṣẹ́ eso Asobode eka akoko nipinle ogun to wa ni idiroko ti gba awon eru fayawo to je Bilionu merin ole #4.6 bn lowo awon onifayawo jakejado ipinle ogun laarin ojo metalelogorin, be ni won si pa Owo to le ni milionu igba ole mokandinlogota wole sapo ijoba apapo lasiko naa.
Adari eso Asobode Oladapo Afeni, sọ èyí fún àwọn oníròyìn nígbà tí wọ́n ń bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ní ọjọ́rú ní Sentry, ni Idiroko,
O fi kún un pé awon eru fayawo ti won gba naa je ogoje ole mefa (146) ti aropo Owo ori eru naa si je ₦4,628,591,970.16 láàárín ọjọ́ kìíní oṣù kẹrin sí ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹfà, èyí tí kò ju ọjọ́ mẹ́tàlélọ́gọ́rin pere lọ.
Ó ní àwọn àpò ìrẹsì tí wọ́n ti sè ní ilẹ̀ òkèèrè tó tó egberunmeta Odin die (2,807),
ìdì Igbo Cannabis sativa je egberunmesan irinwo ati mejilelogorin (9,482),
Marijuana àpò mejilelogota (62)
Epo Bentiro lita egberun-lona-merindinlogun ati edegbeta ole- meedogbon (16,525 liters)
Taya tokunbo igba ole irinwo ole metadonlogbon (2,427)
100 sachets tramadol ti 10 ege 225 mg, àti 77 páálí abẹ́rẹ́ analgin, pelu awon oja fayawo mii.
Afeni tọ́ka sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà alumokoroyi tí àwọn oníṣòwò fayawo naa ma ń lò.
O ni, “Ní ọjọ́ kẹta oṣù kẹfà, àwọn eso Asobode dá ọkọ̀ akẹ́rù kan tí wọ́n kọ “Fún Títa” si Ara re duro ni ọ̀nà Ijebu-Ode, wọ́n sì rí àwọn taya 2,427 tí wọ́n fi pamọ́ sínú rẹ̀.
Ogbon ti awon kan da nipe won lo moto ti Ile ise Dangote fi ma n ko simenti Ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kẹfà, ti awakọ̀ naa si ko iresi si aarin simenti , won gbìyànjú láti da oko re duro kaka ko duro se lo n gbiyanju lati salo mo eso Asobode lowo ni opopona Itori-Wasimi-Abeokuta nigba ti won fi ma daa duro àpò ìrẹsì ogorunkan ati metala (113) ni won ri ninu re.Be ni won mu awako naa ti a si ma gbe lo sile ejo laipe.
Niti awon oogun oloro ti won gba , esekese ni kontirola Afeni ti fa awon oogun oloro ti won gba naa le Ogbeni Ekundayo Williams to soju ajo to n gbogun ti oogun oloro àti olórí ilé iṣẹ́ ìjọba fún ìṣàkóso oúnjẹ àti oògùn, Ogbeni , Adaa Daniels Agangba lowo fun ayewo siwaju sii .
Afeni Fi aidunnu re han si bi awon Igbo ti won n ko wole lati agbegbe Imeko ni ijoba ibile Imeko/Afon ni ipinle ogun se n po sii.
” Se e ri awon Igbo ti a gba yi aipe yi la gba awon Igbo kan ti won Fe ko wole lagbegbe Imeko Afon ti a ti gba eleyi ti e ri yi, emi ati awon osise mi ko ni je ko su wa afi ti a ba reyin awon to n sise naa la ma to duro”.gege bo se so.
” A n sa gbogbo ipa wa lati maa se atileyin fawon ẹgbẹ akeko lati le ma se ilaniloye fawon Odo nipa akoba ti oogun oloro nse fawon eeyan.”
” Awon akeko to wa sibi lati Ile eko gbogbonise ilaro ti won ti so di ifasiti imo ero ti ilaro bayi, ni won ri gbe awon etokan kale ti won ti Fe ma Fi se ilaniloye fawon eeyan to a si to n tiwonleyin. be ni awon akeko mii tun wa sibi lati ilu Abeokuta ti a si n sagbateru awon eto ti won gbe wa Tori a rii pe o ma tun la awon Odo loye nipa akoba ti lilo oogun oloro maa n se fun won”.
” Mo n Fi asiko yi so fawon ti won wa ni agbegbe yi ki won yera fun ise yi tori enikeni ti Owo wa ba tun te ma foju ba Ile ejo.




